Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 29, 2019
ỌSIRÉLÍÀ

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé” ti Ọdún 2019 Tí A Ṣe Ní Melbourne, Lórílẹ̀-Èdè Ọsirélíà

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé” ti Ọdún 2019 Tí A Ṣe Ní Melbourne, Lórílẹ̀-Èdè Ọsirélíà
  • Ọjọ́ Tí A Ṣe É: November 22 sí 24, 2019

  • Ibi Tí A Ti Ṣe É: Pápá Ìṣeré Marvel ní Melbourne, Ọsirélíà

  • Èdè Tí A Lò fún Ìtòlẹ́sẹẹsẹ: Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Ọsirélíà, Chinese Cantonese, Chinese Mandarin, Gẹ̀ẹ́sì, Korean, Sípáníìṣì, Tagalog, Vietnamese

  • Iye Àwọn Tó Pésẹ̀: Ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti méjìlélọ́gọ́rin (46,582)

  • Iye Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: Ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti méje (407)

  • Iye Àwọn Aṣojú Tó Wá Láti Orílẹ̀-Èdè Míì: Ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti mẹ́tàlélọ́gọ́rin (6,083)

  • Àwọn Ẹ̀ka Tí Aṣojú Ti Wá: Ajẹntínà, Kánádà, Hong Kong, Íńdíà, Ítálì, Japan, Kòríà, Philippines, Solomon Islands, South Africa, Taiwan, Amẹ́ríkà

  • Ìrírí: Ọ̀gá àgbà Ọgbà Ẹranko Ballarat sọ pé: “Gbogbo ẹnu ni mo fi ń sọ pé láti bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) tí mo ti ń ṣiṣẹ́ ní Ọgbà Ẹranko Ballarat, àwùjọ yín ni mo tíì gbádùn jù, òun ló sì wà létòlétò jù lọ nínú àwùjọ tí mo ti ń bá ṣiṣẹ́. Mo dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ yín àti lọ́wọ́ àwọn tó mú àwọn èèyàn káàkiri.”

    Ọ̀gá àgbà ilé ìtura tí àwọn àlejò bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ogójì (340) dé sí sọ pé: “Gbogbo wọn máa ń kóra jọ láti yanjú ìṣòro. Ṣe ni wọ́n dà bí ìdílé kan lójú mi tí gbogbo wọn jọ ń sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń ti ara wọn lẹ́yìn. Ká sòótọ́, inú mi dùn gan-an pé mo wà pẹ̀lú wọn. Ọdún kọkànlá (11) tí mo ti ń ṣiṣẹ́ ìgbàlejò rèé, síbẹ̀ àwùjọ wọn ló jọ mí lójú jù.” Torí ohun tí ọ̀gá náà rí, ó lọ sí àpéjọ tá a ṣe lọ́jọ́ Saturday pẹ̀lú àwọn ará..

 

Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ń kí àwọn àlejò káàbọ̀ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Denham Court ní ìgbèríko Sydney, lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà

Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọ gbàgede náà

Àwọn àlejò àtàwọn ará jọ ń kọ orin ìyìn sí Jèhófà

Ọ̀dọ́bìnrin kan dì mọ́ ìyá rẹ̀ lẹ́yìn tó ṣèrìbọmiv

Arákùnrin David Splane tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń sọ ọ̀rọ̀ tó kẹ́yìn lọ́jọ́ Friday

Àwọn àlejò tó wà lẹ́nu àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ń kí àwùjọ tọ̀yàyà-tọ̀yàyà

Àwọn àlejò jọ ń ya fọ́tò

Àwọn arábìnrin kan ń fi ijó dá àwọn àlejò lárayá nígbà àpèjẹ ìrọ̀lẹ́