Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

FEBRUARY 15, 2019
ỌSIRÉLÍÀ

Òjò Àrọ̀ọ̀rọ̀dá Mú Kí Àgbàrá Ya Bo Ìlú Queensland ní Ọsirélíà

Òjò Àrọ̀ọ̀rọ̀dá Mú Kí Àgbàrá Ya Bo Ìlú Queensland ní Ọsirélíà

Àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò ti mú kí alagbalúgbú omi ya bo apá àríwá-gúúsù orílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Omíyalé yìí lé ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn nílé, ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì bà jẹ́ títí kan iná ìjọba.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Ọsirélíà ròyìn pé akéde méjìdínlọ́gọ́ta (58) láti ìjọ mẹ́ta ni omíyalé yìí mú kí wọ́n lọ máa gbé lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tàbí àwọn ará. Ilé mẹ́wàá tó jẹ́ tàwọn ará wa ni àgbàrá ya wọ̀, ó sì ba méjì lára wọn jẹ́ pátápátá.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì ti yan Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù, alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà tó wà lágbègbè náà sì ń bójú tó àwọn akéde tọ́rọ̀ yìí kan. Àdúrà wa ni pé kí àwọn araá wa máa fara dà á nìṣó, kí wọ́n sì rí ìtùnú lọ́dọ̀ àwọn alábòójútó onífẹ̀ẹ́ yẹn.—1 Pétérù 5:2.