Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 13, 2019
ỌSIRÉLÍÀ

Iná Jó Ọ̀pọ̀ Ibi ní Ọsirélíà

Iná Jó Ọ̀pọ̀ Ibi ní Ọsirélíà

Tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan pàdánù ilé wọn nígbà tí iná tó jó léraléra nínú igbó sun mílíọ̀nù kan hẹ́kítà ilẹ̀ (nǹkan bíi mílíọ̀nù méjì ààbọ̀ éékà) jákèjádò ìpínlẹ̀ New South Wales àti ìpínlẹ̀ Queensland ní Ọsirélíà. Kò sí ìkankan nínú àwọn ará wa tó kú tàbí tó fara pa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Kò sì sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí Gbọ̀ngàn Àpéjọ kankan tó bà jẹ́.

Àwọn aláṣẹ ìjọba ìpínlẹ̀ sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn tó ń dáná sun ilé ló bẹ̀rẹ̀ àwọn kan lára iná náà. Láti oṣù September tí iná náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í jó, ó ti pa èèyàn mẹ́fà, ó sì ti jó ilé ó kéré tán ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ààbọ̀ (650) run pátápátá.

Àwọn ará tó tó igba (200) lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ní láti fi ilé wọn sílẹ̀, àmọ́ wọ́n ti pa dà sílé báyìí. Àwọn Ẹlẹ́rìí kan ti ń bójú tó tọkọtaya tí ilé wọn bà jẹ́. Àwọn alàgbà ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tu àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kàn nínú.—Ìṣe 20:28.