Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Tọkọtaya Sa’ad (tó ṣìkejì láti apá òsì) àtàwọn tọkọtaya mẹ́ta míì tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ìwé ẹ̀rí ọjọ́ ìbí àwọn ọmọ wọn

MARCH 2, 2016
PALESTINIAN TERRITORIES

Wọ́n Ń Fi Ẹ̀tọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tó Wà ní Àgbègbè Palẹ́sínì Dù Wọ́n

Wọ́n Ń Fi Ẹ̀tọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tó Wà ní Àgbègbè Palẹ́sínì Dù Wọ́n

Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Mike Jalal àti Natali Sa’ad, Àgbègbè Palẹ́sínì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò ti pọ̀ ni wọ́n sì ń gbé. Àwọn méjèèjì ti ṣègbéyàwó, wọ́n sì ti forúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, àmọ́ wọn ò fún wọn ní ìwé ẹ̀rí. Kódà, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà, ẹnu àìpẹ́ yìí ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ìwé ẹ̀rí ọjọ́ ìbí Andrae, ọmọkùnrin tí wọ́n bí gbà. Àwọn nìkan kọ́ ni irú ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí o. Ohun tójú àwọn tọkọtaya míì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń rí náà nìyẹn. Torí pé orúkọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò sí lábẹ́ òfin Àgbègbè Palẹ́sínì ni ìjọba ṣe ń fi àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tí wọ́n ní dù wọ́n.

Wọ́n Ń Fi Ẹ̀tọ́ Wọn Dù Wọ́n Torí Orúkọ Ẹ̀sìn Wọn Ò Sí Lábẹ́ Òfin

Òjíṣẹ́ kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló so tọkọtaya Sa’ad pọ̀ nígbà tí wọ́n ṣègbéyàwó lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Àmọ́, Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ohun Tó Ń Lọ Lórílẹ̀-èdè ní Àgbègbè Palẹ́sínì kọ̀ láti forúkọ ìgbéyàwó náà sílẹ̀ torí pé orúkọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò sí lábẹ́ òfin níbẹ̀. Ilé Iṣẹ́ Ìjọba náà ò gbà láti forúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ torí pé ìjọba ò fọwọ́ sí ìgbéyàwó wọn, ọmọ àlè ni wọ́n á sì ka ọmọ èyíkéyìí tí wọ́n bá bí sí. Tọkọtaya yìí àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì tó ti lọ́mọ ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ yìí.

Ìjọba Fún Àwọn Ọmọ tí Wọ́n Bí Níwèé Ẹ̀rí Ọjọ́ Ìbí

Lọ́dún 2014, Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ohun Tó Ń Lọ Lórílẹ̀-èdè gbà láti forúkọ àwọn ọmọ tí wọ́n bí sílẹ̀. Inú tọkọtaya Sa’ad dùn pé wọ́n ti forúkọ Andrae ọmọ wọn tí wọ́n bí ní January 30, 2012 sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Inú àwọn òbí Maya Jasmin, Laura, àti Cristian, tí gbogbo wọn wà nínú fọ́tò òkè yìí náà dùn pé Ilé Iṣẹ́ Ìjọba náà ti fún àwọn ọmọ tí wọ́n bí ní ìwé ẹ̀rí, èyí jẹ́ kí wọ́n lè mọ̀ wọ́n sí “Kristẹni.”

Àwọn ọmọ náà ti wá ní àwọn ìwé ìdánimọ̀ tí òfin fọwọ́ sí, wọ́n sì ti lẹ́tọ̀ọ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ láti ṣe ohun táwọn ọmọ yòókù ń ṣe. Wọ́n lè bá àwọn òbí wọn rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè míì, tí wọn ò sì ní dá wọn pa dà níbodè ìlú. Bákan náà, wọ́n ti lè lọ sílé ìwé.

Àwọn Ẹ̀tọ́ Míì tí Wọ́n Ṣì Fi Ń Dù Wọ́n

Ìjọba gbà láti forúkọ àwọn ọmọ wọn sílẹ̀ lóòótọ́, àmọ́ wọn ò gbà láti fún tọkọtaya Sa’ad àtàwọn tọkọtaya míì tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìwé ẹ̀rí ìgbéyàwó. Ìyẹn wá mú káwọn èèyàn kan máa fojú ti kò tọ́ wò wọ́n láwùjọ, wọ́n kà wọ́n sí àwọn tó ń gbéra wọn sùn, tí wọ́n kàn jọ ń gbé.

Torí pé ìjọba ò forúkọ wọn sílẹ̀ bíi tọkọtaya, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn tọkọtaya yìí gbọ́dọ̀ máa san owó orí, kí kálukú sì ní àkáǹtì tiẹ̀ ní báńkì. Tí ọkọ tàbí ìyàwó bá nílò ìtọ́jú pàjáwìrì, wọn ò fún ẹnì kejì rẹ̀ lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu irú ìtọ́jú tí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ̀ máa gbà. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkọ tàbí ìyàwó kú, ẹnì kejì rẹ̀ àtàwọn ọmọ wọn ò lè jogún ohun ìní ẹni tó kú. Àwọn tó jẹ́ Kristẹni ò lè sin òkú olólùfẹ́ wọn bí ẹ̀sìn wọn ṣe gbà. Àfi kí wọ́n lọ sin wọ́n síbi ìsìnkú àwọn Mùsùlùmí, lápá ibì kan tí wọ́n yà sọ́tọ̀ níbẹ̀ fáwọn tí kì í ṣe Mùsùlùmí.

Wọ́n Sapá Kí Wọ́n Lè Forúkọ Ẹ̀sìn Wọn Sílẹ̀

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀wé sí àwọn aláṣẹ Àgbègbè Palẹ́sínì ní September 2010 kí wọ́n lè forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Ọdún méjì kọjá, wọn ò rí èsì kankan gbà. Wọ́n wá kọ̀wé sí Ilé Ẹjọ́ Gíga ní Ramallah pé àwọn fẹ́ forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Àmọ́ ní October 2013, ilé ẹjọ́ wọ́gi lé ìwé tí wọ́n kọ.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò dúró látìgbà yẹn, wọ́n ti gbé ìgbésẹ̀ lóríṣiríṣi, wọ́n sì ti lọ bá àwọn aláṣẹ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Àmọ́ ibi pẹlẹbẹ ni ọ̀bẹ ń fi lélẹ̀ torí ibi tí wọ́n bá ọ̀rọ̀ náà dé ló ṣì wà, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ò tíì ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe.

Philip Brumley tó jẹ́ agbẹjọ́rò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún [100] ọdún tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń gbé nílùú Ramallah àti àgbègbè rẹ̀. Wọ́n mọrírì bí ìjọba ṣe gbà wọ́n láyè láti máa jọ́sìn, tí wọn ò sì yọ wọ́n lẹ́nu. Àmọ́ torí pé wọn ò ka ẹ̀sìn wọn sí kò jẹ́ kí wọ́n gbà láti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, ìyẹn wá ń jẹ́ kí wọ́n máa fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tí wọ́n ní dù wọ́n, kò sì yẹ kó rí bẹ́ẹ̀.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé ohun tó dáa ni bí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Palẹ́sínì ṣe fún àwọn ọmọ wọn ní ohun tí wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ sí, ìyẹn ìwé ẹ̀rí ọjọ́ tí wọ́n bí wọn. Àmọ́, àwọn tọkọtaya tí ò tíì rí ìwé ẹ̀rí ìgbéyàwó gbà ń retí pé ìjọba máa wá nǹkan ṣe sí gbogbo ọ̀rọ̀ yòókù tó jẹ mọ́ ẹ̀tọ́ kálukú, wọ́n á sì wá gbà kí wọ́n forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀.