DECEMBER 1, 2020
PAPUA NEW GUINEA
A Mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde Lédè Hiri Motu
Arákùnrin Kegawale Biyama, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Papua New Guinea mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Hiri Motu. A gba àsọyé náà sílẹ̀ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Port Moresby, àwọn èèyàn tó ju ẹgbẹ̀rún méje (7,000) sì gbádùn ẹ̀ ní November 28, 2020.
Papua New Guinea ni wọ́n ti ń sọ èdè tó pọ̀ jù lọ láyé, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti ogójì (840) èdè ni wọ́n ń sọ níbẹ̀. Ọ̀kan lára èdè àjùmọ̀lò mẹ́ta tí wọ́n ń sọ ni èdè Hiri Motu. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogóje (140,000) èèyàn ló ń sọ èdè yìí.
Arákùnrin Kukuna Jack, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Papua New Guinea sọ pé: “Ọjọ́ pẹ́ táwọn tó ń sọ èdè Hiri Motu ti ń retí Bíbélì yìí. Ó dá wa lójú pé wọ́n máa gbádùn ẹ̀ torí pé ìtúmọ̀ ẹ̀ rọrùn lóye, ó sì wọni lọ́kàn.”
Àwọn atúmọ̀ èdè mẹ́fà ló túmọ̀ Bíbélì náà. Atúmọ̀ èdè kan sọ pé: “Ó dájú pé inú àwọn tó ń ka Bíbélì yìí máa dùn nígbà tí wọ́n bá ń rí orúkọ Ọlọ́run nínú ẹ̀ láti Jẹ́nẹ́sísì dé Ìfihàn. Inú wa dùn gan-an pé Jèhófà fún wa ní Bíbélì yìí!”
Bá a ṣe ń ronú lórí àwọn nǹkan tá a ṣe láti túmọ̀ Bíbélì yìí, àwa náà ń sọ bíi ti wòlíì Àìsáyà pé: “Jèhófà, o máa fún wa ní àlàáfíà, torí pé gbogbo ohun tí a ṣe, ìwọ lo bá wa ṣe é.”—Àìsáyà 26:12.