Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

OCTOBER 17, 2019
PERU

Àkànṣe Ìwàásù Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Aymara Nílùú Puno, Lórílẹ̀-Èdè Peru

Àkànṣe Ìwàásù Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Aymara Nílùú Puno, Lórílẹ̀-Èdè Peru

Láti May 1 sí August 31, 2019, ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Peru ṣètò àkànṣe ìwàásù kan kí wọ́n lè wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn ará Peru tí wọ́n ń sọ èdè ìbílẹ̀ tó ń jẹ́ Aymara. Àkànṣe ìwàásù náà kẹ́sẹ járí gan-an ni. Àwọn tó lọ́wọ́ nínú ẹ̀ fi ìwé ẹgbẹ̀rún méje, ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún (7,893) sóde, wọ́n sì fi fídíò wa han àwọn èèyàn ní ìgbà ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún (2,500). Nígbà tí àkànṣe ìwàásù náà fi máa parí, àwọn ará wa ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti mọ́kànlélọ́gọ́rin (381) èèyàn.

Àwọn tó ń sọ èdè Aymara lórílẹ̀-èdè Peru tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta-lé-ní-irínwó (450,000), ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún (300,000) lára wọn tó ń gbé ní ìlú Puno. Ní báyìí, iye àwọn akéde tó ń sọ èdè Aymara jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti mọ́kànlélọ́gbọ̀n (331), wọ́n wà ní ìjọ méje àti àwùjọ mẹ́jọ. Ìpínlẹ̀ ìwàásù tó wà lórílẹ̀-èdè Peru fẹ̀ ju ohun tí àwọn akéde tó wà níbẹ̀ lè kárí lọ, torí náà àwọn akéde tó ń sọ èdè Aymara lórílẹ̀-èdè Chile wá dara pọ̀ mọ́ wọn fún àkànṣe ìwàásù náà. Kí àwọn ará lè dé ọ̀dọ̀ àwọn tó ń sọ èdè Aymara, ìgbà míì wà tí wọ́n máa ń gun òkè tó fi ẹgbẹ̀rún márùn-un (5,000) mítà ga ju ìtẹ́jú òkun lọ, wọ́n á sì wàásù níbi tó tutù bíi yìnyín.

Àwùjọ kan fi ọ̀pọ̀ wákàtí rìn lọ sí agbègbè kan tí àwọn tó ti abúlé míì wá ti wá ṣe ìsìnkú kan. Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin fi ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa àwọn tó ti kú hàn wọ́n nínú Bíbélì. Àwọn aláṣẹ abúlé náà àti ìdílé tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin náà fún gbogbo ìsapá tí wọ́n ṣe kí wọ́n lè wá fi Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tù wọ́n nínú.

Ní apá ibòmíì, àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa rí àwùjọ àwọn èèyàn kan tí wọ́n ń pàdé lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ láti kẹ́kọ́ọ̀ Bíbélì. Àwọn akéde náà rí i pé ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí àti Ìwé Ìtàn Bíbélì tí wọ́n gbà lọ́wọ́ ìbátan wọn kan lórílẹ̀-èdè Bòlífíà ni wọ́n ń lò. Bí àwọn èèyàn yìí ṣe rí i pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ àwọn ìwé tí wọ́n ń lò yìí ni ọ̀pọ̀ lára wọn ti bẹ̀rẹ̀ síí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì ń wá sí àwọn ìpàdé wa.

Arákùnrin Albert Condor, alàgbà kan tó ṣe kòkáárí ọ̀kan lára àwọn àwùjọ náà sọ pé: “Inú èmi àti ìyàwó mi dùn gan-an pé ó ṣeé ṣe fún wa láti lọ́wọ́ nínú àkànṣe ìwàásù yìí. Ó ti jẹ́ ká túbọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jèhófà torí pé nígbà tá a kọ́kọ́ ń lọ sí ìlú náà, a ò mọ bá ṣe máa débẹ̀, torí pé ìrìn-àjò náà nira gan-an. Nígbà tá a débẹ̀, a gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ ká rí ibi tá a máa sùn sí, ó sì gbọ́ àdúrà wa. Àwọn àdúrà tá a gbà yẹn fún mi lókun gan-an, bí mo tún ṣe rí bí àwọn ará yòókù ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà náà tún fún mi lókun.”

Inú àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin dùn pé àwọn wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó lè mú kéèyàn jogún ìyè àìnípẹ̀kun, fún àwọn ará ìlú Puno tí wọ́n ń sọ èdè Aymara lórílẹ̀-èdè Peru.​—Ìfihàn 22:17.