Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Fọ́tò àwọn aṣojú méjì láti Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Thailand (àárín lápá ọ̀tún) ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Peru pẹ̀lú ìgbìmọ̀ ẹ̀ka àtàwọn ará tó ń gbé ibẹ̀.

OCTOBER 9, 2018
PERU

Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Thailand “Gbóríyìn àti Òṣùbà” Fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Nílẹ̀ Peru Torí Wọ́n Ṣèrànwọ́ Fáwọn Ọmọ Ilẹ̀ Thailand Tó Wà Lẹ́wọ̀n

Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Thailand “Gbóríyìn àti Òṣùbà” Fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Nílẹ̀ Peru Torí Wọ́n Ṣèrànwọ́ Fáwọn Ọmọ Ilẹ̀ Thailand Tó Wà Lẹ́wọ̀n

Ní June 26, 2018, àwọn aṣojú Ilé Iṣẹ́ Ìjọba ilẹ̀ Thailand ní Peru wá sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Lima, tó jẹ́ olú ìlú ilẹ̀ Peru. Wọ́n dìídì wá ni láti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ará wa torí pé wọ́n ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọ ilẹ̀ Thailand tó wà lẹ́wọ̀n nílẹ̀ Peru.

Ọdún 2007 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Peru ti bẹ̀rẹ̀ sí í lọ wo àwọn ẹlẹ́wọ̀n kí wọ́n lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ látọdún 2013, àwọn ará bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n kan tí àwọn ọmọ ilẹ̀ Thailand wà. Inú aṣojú ilẹ̀ Thailand yìí dùn gan-an sí ìfẹ́ táwọn ará dìídì fi hàn yìí, ló bá kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì pé òun máa fẹ́ wá síbẹ̀.

Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń jáde bọ̀ láti ọgbà ẹ̀wọ̀n kan tí wọ́n ti lọ kọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Àwọn tí wọ́n wá láti ọ́fíìsì ìjọba ni Ọ̀gbẹ́ni Angkura Kulvanij tó jẹ́ aṣojú mínísítà; Ọ̀gbẹ́ni Pathompong Singthong tó jẹ́ akọ̀wé àgbà àti Pradthana Pongudom tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ aṣojú ilé iṣẹ́. Bí wọ́n ṣe ń rìn káàkiri ẹ̀ka ọ́fíìsì náà, àwọn arákùnrin tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka jẹ́ kí wọ́n rí iṣẹ́ ribiribi tí à ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìtumọ̀, lára ẹ̀ ni bá a ṣe ń túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa sí èdè ìbílẹ̀ mẹ́sàn-án.

Àwọn aṣojú Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Thailand ń wo arákùnrin kan bó ṣe ń túmọ̀ ìtẹ̀jáde wa sí Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Peru.

Nínú lẹ́tà tí wọ́n kọ láti ọ́fíìsì ìjọba sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, wọ́n sọ pé, wọ́n “gbóríyìn àti òṣùbà” fún àwọn ará wa lórí iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ṣe láti ṣèrànwọ́ fún “àwọn aláìní àtàwọn tí ò léèyàn ní Peru, láìka ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àti àṣà wọn sí.” Ilé iṣẹ́ ìjọba tún sọ̀rọ̀ nípa “iṣẹ́ ribiribi àti ìtìlẹyìn táwọn òṣìṣẹ́ Association of Jehovah’s Witnesses ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Peru ń ṣe láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọ ilẹ̀ Thailand tó wà lẹ́wọ̀n nílẹ̀ Peru.”

Ohun táwọn ará wa ní Peru ń ṣe jẹ́ ká rí àyípadà rere tó máa ń wáyé tá a bá ń kọ́ gbogbo èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.—1 Kọ́ríńtì 9:22.