Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 8, 2019
PHILIPPINES

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì í Yẹ̀ Láé!” Manila, Philippines—2019

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì í Yẹ̀ Láé!” Manila, Philippines—2019
  • Ọjọ́: November 1-3, 2019

  • Ibi Tí Wọ́n Ti Ṣe é: Gbọ̀ngàn Mall of Asia Arena àti SMX Convention Center ní Manila, Philippines

  • Àwọn Èdè Tí Wọ́n Lò: English, Tagalog

  • Iye Àwọn Tó Wá: 26,245

  • Iye Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 145

  • Iye Àwọn Tó Wá Láti Ilẹ̀ Òkèèrè: 5,397

  • Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tá a Pè: Australasia, Central Europe, France, Indonesia, Italy, Japan, Kazakhstan, Madagascar, Malaysia, Myanmar, Papua New Guinea, Solomon Islands, South Africa, Sri Lanka, Taiwan, Thailand, United States

  • Àwọn Ìrírí: Rogelio Jolongbayan tó jẹ́ máníjà tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn oníbàárà ní gbọ̀ngàn Asia Arena sọ pé: “Ẹ̀yin lẹ níwà ọmọlúwàbí jù nínú gbogbo àwọn tó ti ń lo ibí. Inú wa dùn pé ẹ wá síbí.”

    Ọ̀gá ọlọ́pàá kan lórílẹ̀-èdè Philippines náà sọ pé: “Ṣe làwọn àlejò náà tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ wọnú gbọ̀ngàn náà, ó sì wúni lórí gan an. Mi ò rò pé wọ́n nílò wa níbí tó bá jẹ́ pé báyìí ni nǹkan ṣe ń lọ!”

    Teofilo Labe Jr. tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún alábòójútó fún ọ̀rọ̀ ààbò ní Manila Hotel ni wọ́n ní kó rí sí bí àwọn àlejò ṣe máa rìnrìn àjò afẹ́. Lẹ́yìn tó kíyè sí bí nǹkan ṣe ń lọ fúngbà díẹ̀, ó wá sọ pé: “Tí àwọn aláṣẹ bá ní kí n díwọ̀n bí ẹ ṣe ṣètò ara yín sí, màá sọ pé ẹ̀yin lẹ ṣe dáadáa jù. Ẹ wà létòlétò gan an ni.”

 

Àwọn ará ń kí àwọn àlejò káàbọ̀ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Philippines

Àwọn ará ń pín ìwé ìkésíni ṣáájú àpéjọ náà.

Àwọn aṣojú mẹ́rin láti ẹ̀ka ọ́fíìsì ń dáhùn ìbéèrè àwọn oníròyìn kí àpéjọ náà tó bẹ̀rẹ̀

Àwọn tó wá sí àpéjọ náà wà níta gbọ̀ngàn àpéjọ náà

Àwọn aṣojú láti ilẹ̀ òkèèrè ń ya fọ́tò pẹ̀lú àwọn ará tó wà lágbègbè náà

Àwọn ará ń kọrin Ìjọba Ọlọ́run lásìkò àpéjọ náà

Àwọn arákùnrin méjì ń ṣèrìbọmi lọ́jọ́ Sátidé

Arákùnrin Mark Sanderson tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń sọ àsọyé tó kẹ́yìn lọ́jọ́ Sátidé

Àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tí wọ́n wá dara pọ̀ mọ́ Arákùnrin Sanderson lórí pèpéle lọ́jọ́ tó gbẹ̀yìn àpéjọ náà

Àwọn ará ń jó ijó ìbílẹ̀ ìlú Philippine tí wọ́n ń pè ní Tinikling nígbà tí wọ́n kóra jọ lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́