JUNE 22, 2021
PHILIPPINES
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde Lédè Bicol
Ní June 20, 2021, a mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde ní ẹ̀dà ti orí ẹ̀rọ ní èdè Bicol. Arákùnrin Denton Hopkinson tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Philippines ló mú Bíbélì yìí jáde nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ pàtàkì kan ṣe látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tí wọ́n sì ṣàtagbà ẹ̀ sáwọn ará tó wà láwọn ìjọ mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún (97).
Àwọn Ìsọfúnni Pàtàkì Nípa Iṣẹ́ Náà
Nǹkan bí mílíọ̀nù márùn-ún àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ èèyàn ló ń sọ èdè Bicol, ìpínlẹ̀ márùn-ún lórílẹ̀-èdè Philippines sì ni wọ́n ń gbé. Àwọn ìpínlẹ̀ náà ni: Albay, Camarines Norte, Camarines Sur, Catanduanes àti Sorsogon.
Èdè yìí ni èdè kárùn-ún tí wọ́n ń sọ jù lórílẹ̀-èdè Philippines
Àwọn akéde tó ju ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (5,800) ló wà láwọn ìjọ tó ń sọ èdè Bicol
Ọdún méje àtààbọ̀ ni àwùjọ atúmọ̀ èdè méjì fi ṣiṣẹ́ lórí Bíbélì yìí
Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè náà sọ pé: “Oríṣiríṣi èdè ìbílẹ̀ tó yàtọ̀ síra ló wà nínú èdè Bicol. Torí náà, a sapá gan-an láti wá àwọn ọ̀rọ̀ tó máa yé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ èdè Bicol.”
Atúmọ̀ èdè míì sọ pé: “Ó dá wa lójú pé ìtumọ̀ tó ṣe kedere, tí ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ sì jẹ́ tòde òní yìí á jẹ́ káwọn tó ń kà á lóye Bíbélì.”
Ní orílẹ̀-èdè Philippines, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí a tún ṣe ti wà lódindi làwọn èdè ìbílẹ̀ mẹ́fà míì. Àwọn èdè náà ni: Cebuano, Hiligaynon, Iloko, Pangasinan, Tagalog àti Waray-Waray.
A báwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó ń sọ èdè Bicol yọ̀ fún Bíbélì tí wọ́n mú jáde láìpẹ́ yìí. Ó dá wa lójú pé Bíbélì yìí máa ran àwọn èèyàn púpọ̀ sí i lọ́wọ́ láti yin Jèhófà, kí wọ́n sì “gbádùn ayé títí láé.”—Sáàmù 22:26.