APRIL 3, 2019
PHILIPPINES
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde Lédè Mẹ́ta ní Philippines
Ní oṣù January 2019, Arákùnrin Mark Sanderson tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí mú Bíbélì jáde lédè Cebuano, Tagalog àti Waray-Waray láwọn ibi àkànṣe ìpàdé kan. Gbọ̀ngàn ìwòran Hoops Dome tó wà ní ìlú Lapu-Lapu ni wọ́n ti mú Bíbélì èdè Cebuano jáde ní January 12. Lọ́jọ́ kejì, a mú ti èdè Waray-Waray jáde, wọ́n sì pín in ní Gbọ̀ngàn Leyte Academic Center tó wà ní ìlú Palo lágbègbè Leyte. Ní January 20, a mú Bíbélì jáde lédè Tagalog ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ Metro Manila tó wà ní ìlú Quezon City.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba la ta àtagbà àwọn àkànṣe ìpàdé náà sí, ó sì lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélọ́gọ́jọ (163,000) Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a pín fáwọn tó wá.
Arákùnrin Dean Jacek tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Philippines sọ pé: “Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe la mú jáde lédè Cebuano àti Tagalog. Ó lé lọ́dún mẹ́ta kí wọ́n tó parí iṣẹ́ lórí ọ̀kọ̀kan wọn. A ti ní Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tẹ́lè lédè Waray-Waray, àmọ́ ìgbà àkọ́kó nìyí táwọn tó ń ka èdè yìí máa ní odindi Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ó lé lọ́dún márùn-ún tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ ìtúmọ̀ rẹ̀.”
Tá a bá pín àwọn tó ń gbé ní Philippines sọ́nà mẹ́wàá, àwọn tó ń sọ èdè Cebuano, Tagalog tàbí Waray-Waray lé ní ìdá mẹ́fà. Lára wọn ni nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́jọ (160,000) àwọn ará wa àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì ó dín mẹ́ta (197,000) àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Yàtọ̀ síyẹn, ní báyìí, ẹgḅẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ ilẹ̀ Philippines tó ń gbé láwọn ilè míì náà máa lè gbádùn gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun láwọn èdè yìí.
Arábìnrin Donica Jansuy tó wà ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Tagalog ní Amẹ́ríkà sọ bó ṣe rí lẹ́yìn tó wa Bíbélì náà jáde lórí íńtánẹ́ẹ̀tì pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tí wọ́n tún ṣe lédè Tagalog yìí rọrùn gan-an, ó ṣe kedere, ó sì jẹ́ kó tètè yéèyàn. Ọ̀rọ̀ tó rọrùn tó wà nínú ẹ̀ ń jẹ́ kó ṣe wá bíi pé Jèhófà ń bá wa sọ̀rọ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ó sì mú kí ohun tó wà nínú Bíbélì túbọ̀ wọ̀ni lọ́kàn.”
Ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lódindi tàbí lápá kan ní èdè mọ́kàndínlọ́gọ́sàn-án (179). A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó ń mú kí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí wọ́n túmọ̀ lọ́nà tó ṣe kedere dé ọ̀dọ̀ àwọn ará wa àtàwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.—Ìṣe 13:48.