Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 13, 2019
PHILIPPINES

Ìjì Líle Ba Apá Kan Orílẹ̀-èdè Philippines Jẹ́

Ìjì Líle Ba Apá Kan Orílẹ̀-èdè Philippines Jẹ́

Ìjì líle typhoon Kammuri táwọn èèyàn Philippines tún ń pè ní Tisoy jà lórílẹ̀-èdè Philippines ní December 2, ọdún 2019. Àgbègbè Bicol ní ìpínlẹ̀ Luzon ni ìjì náà ti jà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan tó kú tàbí tó fara pa, ilé àwọn Ẹlẹ́rìí méjìdínláàádọ́fà (108) ló bà jẹ́ gan-an, nígbà tí ilé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé méjìdínlọ́gọ́rin (478) bà jẹ́ díẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) ló bà jẹ́.

Torí bí ìjì náà ṣe ba nǹkan jẹ́ ní ibi tó pọ̀ gan-an, ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Philippines ṣètò Ìgbìmọ̀ mẹ́jọ Tó Ń Pèsè Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù, kí wọ́n lè fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbé àwọn ará ró kí wọ́n sì tún ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tara.

À ń gbàdúrà fún àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Philippines, à ń bẹ Jèhófà bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Kí Jèhófà dá ọ lóhùn ní ọjọ́ wàhálà. . . .  Kó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ibi mímọ́.”—Sáàmù 20:1, 2.