Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 12, 2020
PHILIPPINES

Ìjì Líle Méjì Ṣọṣẹ́ Láwọn Apá Ibì Kan Lórílẹ̀-Èdè Philippines

Ìjì Líle Méjì Ṣọṣẹ́ Láwọn Apá Ibì Kan Lórílẹ̀-Èdè Philippines

Ibi tó ti ṣẹlẹ̀

Apá gúúsù erékùṣù Luzon àtàwọn erékùṣù míì tó yí i ká

Ohun tó ṣẹlẹ̀

  • Ní October 25, 2020, ìjì líle Molave, tí wọ́n mọ̀ sí Quinta lórílẹ̀-èdè Philippines ṣọṣẹ́ ní ìlú Albay, lágbègbè Bicol tó wà lérékùṣù Luzon lórílẹ̀-èdè Philippines. Lẹ́yìn ìyẹn, ìjì líle yìí tún jà láwọn agbègbè míì tó wà lérékùṣù Luzon

  • Ní November 1, 2020, ìjì líle tí wọ́n ń pè ní Goni, tí wọ́n mọ̀ sí Rolly lórílẹ̀-èdè Philippines jà ní Catanduanes, tó jẹ́ erékùṣù míì ní Bicol lágbègbè Luzon. Ìjì líle yìí lágbára gan-an débi pé ó tún ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́ láwọn agbègbè tí ìjì Molave ti ṣọṣẹ́ tẹ́lẹ̀

  • Ìjì líle méjèèjì fa òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá àti atẹ́gùn tó lágbára, ó tún fa omíyalé tó ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́ títí kan iná mànàmáná, ọ̀pọ̀ èèyàn ò sì rí omi tí wọ́n lè mu. Bákan náà, kò ṣeé ṣe fáwọn tó ń gbé láwọn àdúgbò yẹn láti lo fóònù àti íńtánẹ́ẹ̀tì

  • Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá yẹn mú kí ẹrẹ̀ ya látorí Mount Mayon, ó sì ba ọ̀pọ̀ ilé tó wà nítòsí òkè náà jẹ́

Bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe kan àwọn ará wa

  • Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ni ìjì yẹn ti lé kúrò nílé

  • Arábìnrin kan tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún (89) ṣèṣe díẹ̀ nígbà tó ń sá kúrò nílé, ilé yẹn sì bà jẹ́ pátápátá

Àwọn nǹkan tó bà jẹ́

  • Ilé mẹ́rìnléláàádóje (134) àti Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́jọ bà jẹ́ díẹ̀

  • Ilé márùndínlọ́gọ́rin (75) àti Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́jọ bà jẹ́ gan-an

  • Ilé mọ́kànlélọ́gọ́rùn-ún (101) àti Gbọ̀ngàn Ìjọba kan bà jẹ́ kọjá àtúnṣe

Bá a ṣe ran àwọn ará wa lọ́wọ́

  • Ìgbìmọ̀ mẹ́fà tó ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù, àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà ń ṣiṣẹ́ pọ̀ láti pèsè ohun táwọn ará wa nílò, bí oúnjẹ, omi, ilé àtàwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì. Bí wọ́n ṣe ń pèsè ìrànwọ́ fáwọn ará wa, tí wọ́n sì ń tù wọ́n nínú, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe, kí wọ́n má bàa tẹ òfin lójú, ìyẹn òfin táwọn elétò ààbò ṣe nípa àrùn Corona

A ò ní dákẹ́ àdúrà lórí àwọn ará wa tí wọ́n wà lágbègbè tí àjálù yìí ti ṣẹlẹ̀. Ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní fi wọ́n sílẹ̀, á máa bá a lọ láti jẹ́ “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” lásìkò tí nǹkan nira fún wọn yìí.​—2 Kọ́ríńtì 1:3.