NOVEMBER 23, 2020
PHILIPPINES
Ìjì Líle Vamco Tún Ṣọṣẹ́ Láwọn Ibi Tí Ìjì Ti Bà Jẹ́ Léraléra Lórílẹ̀-èdè Philippines
Ibi tó ti ṣẹlẹ̀
Luzon
Ohun tó ṣẹlẹ̀
Ní November 11, 2020, ìjì líle Vamco (tí wọ́n tún ń pè ní Ulysses) ṣọṣẹ́ ní Patnanungan tó wà lágbègbè Quezon. Ó tún ṣọṣẹ́ lọ́pọ̀ ibi lérékùṣù Luzon
Èyí ni ìgbà kọkànlélógún (21) tí ìjì líle máa jà lórílẹ̀-èdè Philippines lọ́dún yìí, ó sì fa omíyalé tó pọ̀ gan-an
Ìjì líle Goni làwọn èèyàn gbà pé ó tíì ṣọṣẹ́ jù lọ lórílẹ̀-èdè Philippines látọdún 2013, àmọ́ kò pé ọ̀sẹ̀ méjì tí ìjì yìí jà lérékùṣù Luzon ni ìjì líle Vamco tún jà
Ọ̀yamùúmùú òjò àti ìjì tó ń jà léraléra mú káwọn adágún tí wọ́n fi ń dá omi dúró kún kọjá àlà. Torí náà, ìjọba ní láti tú omi yìí sílẹ̀, ìyẹn sì fa omíyalé láwọn ibi tí ìjì líle Vamco ò dé
Bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe kan àwọn ará wa
Ìdílé tó ju ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ni àkúnya omi lé kúrò nílé. Omi yẹn pọ̀ débi pé ọ̀pọ̀ lára wọn ní láti gun orí òrùlé kí wọ́n tó wá gbà wọ́n sílẹ̀
Èéfọ́ ìgò gbá ọ̀dọ́kùnrin kan lójú, ó sì ṣèṣe. Àmọ́ ara ẹ̀ ti ń yá
Àwọn nǹkan tó bà jẹ́
Ìròyìn tá a kọ́kọ́ gbọ́ ni pé:
Ó kéré tán, omi ya wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́fà àti ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè kan
Ó kéré tán, ilé tó tó ogún (20) ló bà jẹ́
Ilé kan bà jẹ́ pátápátá
Bá a ṣe ran àwọn ará wa lọ́wọ́
Àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà kọ́kọ́ ṣètò báwọn ará ṣe máa rí àwọn nǹkan tí wọ́n nílò, bí oúnjẹ, omi, aṣọ, ilé àtàwọn nǹkan míì
Àwọn ìdílé kan ti pa dà sílé kí wọ́n lè tún ilé wọn ṣe
A ti ṣètò ìgbìmọ̀ mẹ́ta kí wọ́n lè máa pèsè ìrànwọ́ fáwọn ará wa
Bí wọ́n ṣe ń pèsè ìrànwọ́ fáwọn ará, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe, kí wọ́n má bàa tẹ òfin lójú, ìyẹn òfin táwọn elétò ààbò ṣe nípa àrùn Corona
Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa dúró ti àwọn ará wa lásìkò tí nǹkan nira yìí. À ń retí ìgbà tí gbogbo àwa èèyàn Jèhófà á máa gbé lálàáfíà àti ààbò, tá ò sì ní máa bẹ̀rù àjálù tó ń ba àyíká jẹ́.—Sáàmù 4:8.