Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lápá òsì: Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ìjì lílé bà jẹ́. Lápá ọ̀tún: Àwòrán ilẹ̀ tó ń fi àwọn ibi tí ìjì náà bà jẹ́ hàn

MAY 28, 2020
PHILIPPINES

Ìjì Líle Vongfong Jà Lórílè-èdè Philippines Lásìkò Tí Ìjì Sábà Máa Ń Jà

Ìjì Líle Vongfong Jà Lórílè-èdè Philippines Lásìkò Tí Ìjì Sábà Máa Ń Jà

Ìjì líle Vongfong (tí wọ́n tún ń pè ní Ambo) jà ní erékùṣù Samar ní May 14, 2020. Ìgbà àkọ́kọ́ tí irú ìjì líle yìí máa jà lọ́dún 2020 nìyẹn, Ìwọ̀ Oòrùn Òkun Pàsífíìkì ló sì ti jà. Ìjì náà ṣọṣẹ́ gan-an ní erékùṣù Samar. Kódà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló kó kúrò lágbègbè yẹn, èyí ò sì rọrùn rara torí ìjọba ti ṣòfin pé káwọn èèyàn máa jìnnà síra torí àrùn tó wà lóde.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sí ìkankan nínú àwọn ará wa tó fara pa, àwọn mọkàndínlọ́gọ́ta (59) ló ní láti fi ilé wọn sílẹ̀. Àwọn kan lọ ń gbé ní iléèwé tí wọ́n ṣètò pé káwọn èèyàn sá sí, àwọn míì sì lọ ń gbé ní ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi tiwọn. Yàtọ̀ síyẹn, ilé àwọn ará méjìlélọ́gọ́rin (82) ni ìjì náà bà jẹ́. Kódà, Gbọ̀ngàn Ìjọba márùn-ún ló bà jẹ́, ìkan sì wó lulẹ̀ pátápátá. Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Philippines dá Ìgbìmọ̀ Tó Ń Pèsè Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù sílẹ̀, kí wọ́n lè fún àwọn ará wa tí ìjì náà ṣàkóbá fún ní ohun tí wọ́n nílò nípa tara, kí wọ́n sì tún fún ìgbàgbọ́ wọn lókun.

A ò ní dákẹ́ àdúrà lórí àwọn ará wa ní Philippines, tí wọ́n ń fara da ọṣẹ́ tí ìjì líle àti àrùn corona ń fà. Ó dá wa lójú pé Jèhófà tó jẹ́ “àpáta ayérayé” á máa pèsè ohun táwọn ará wa nílò lásìkò tí nǹkan le koko yìí.​—Àìsáyà 26:4.