MAY 12, 2020
PHILIPPINES
Ìjọ Ṣèrànwọ́ fún Arábìnrin Kan Tó Jẹ́ Adití àti Afọ́jú Lákòókò Àjàkálẹ̀ Àrùn
Arábìnrin Cynthia Pablo ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta (64) jẹ́ akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi tó ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ Panghulo lórílẹ̀-èdè Philippines, èdè àwọn adití ni wọ́n ń sọ ní ìjọ náà. Adití ni obìnrin yìí, ó fọ́jú, kò sì fi bẹ́ẹ̀ rí jájẹ. Ó ń gbé pẹ̀lú àwọn ìbátan rẹ̀ tí kìí ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní apá ibi térò pọ̀ sí ní Valenzuela City. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé, ipò tí Cynthia wà ò rọrùn nítorí àwọn ìpèníjà tó ní, èyí tí àjàkálẹ̀ àrùn tó gbòdekan yìí ti mú kó burú sí i, àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú ìjọ ẹ̀ ń ṣètọ́jú ẹ̀, wọn sì ń pèsè ohun tó nílò fún-un.
Nítorí ọjọ́ orí ẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn COVID 19 lè tètè ran Cynthia kó sì ṣàkóbá fún un. Àjàkálẹ̀ àrùn yìí tí mú kó ṣòro láti rí omi lágbègbè ẹ̀, ìyẹn sì ti mú kó ṣòro fún-un láti fọ aṣọ ẹ̀. Kí àjàkálẹ̀ àrùn yìí tó bẹ̀rẹ̀, àwọn arábìnrin nínú ìjọ tí Cynthia ń dara pọ̀ mọ́ máa ń ràn án lọ́wọ́, àmọ́ àwọn ìkálọ́wọ́kò tí ìjọba kéde láìpẹ́ yìí ti mú kí èyí má ṣeé ṣe.
Arákùnrin Walter Ilumin tó jẹ́ alàgbà kan nínú ìjọ ẹ̀ lọ gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ pé kí wọ́n fún òun láyè láti jáde nílé kó lè lọ tọ́jú Cynthia. Àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ pàtàkì làwùjọ nìkan ni ìjọba máa ń fún ní ìyọ̀ǹda yìí. Láfikún sí fífọ aṣọ ẹ̀, Walter tún mú oúnjẹ àti àwọn ohun kòṣeémáàní míì wá fún-un. Ó rí i dájú pé òun tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni àti ìlànà ìjọba lórí ààbò ara ẹni, bíi lílo ìbòmú àti àwọn ohun ìdáàbòbò míì, ó sì máa ń fọwọ́ lóòrèkóòrè.
Cynthia máa ń ṣe fídíò kékeré kó lè fi sọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ fáwọn ará tó ń tọ́jú ẹ̀. Arákùnrin Ilumin sì máa ń fi àwọn fídíò náà han àwọn ará ìjọ.
Alàgbà yìí tún máa ń lọ sí ilé arábìnrin Cynthia láti túmọ̀ ìpàdé ìjọ táà ń ṣe látorí ẹ̀rọ sí èdè àwọn tó dití tó sì jẹ́ afọ́jú. Pẹ̀lú ìrànwọ́ yìí, Cynthia lè dáhùn déédéé nípàdé nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Bó ṣé ń kópa nínú ìpàdé lákòókò àjàkálẹ̀ àrùn ti jẹ́ orísun ìṣírí fún àwọn ará yòókù tó wà nípàdé.
Ó dá wa lójú pé, inú Jèhófà dùn láti rí àwọn èèyàn ẹ̀ tó ń pèsè ìtùnú àti ìrànwọ́ fúnra wọn ‘ní pàtàkì jù lọ bí a ṣe ń rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.’—Hébérù 10:24, 25.