NOVEMBER 18, 2019
PHILIPPINES
Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Pọ̀ Gan-an Wáyé ní Apá Gúúsù Orílẹ̀-Èdè Philippines
Láti October 16, 2019, léraléra ni ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára wáyé ní apá gúúsù orílẹ̀-èdè Philippines. Àwọn èèyàn mọ́kànlélógún (21) ló kú, àwọn tó lé ní irínwó (400) ló fara pa, àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùndínlógójì (35,000) ló sì ní láti fi ilé wọn sílẹ̀. Mẹ́ta lára àwọn ìmìtìtì ilẹ̀ náà lágbára gan-an, kódà ilẹ̀ ṣì ń mì lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọjọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé arábìnrin kan fara pa díẹ̀, a dúpẹ́ pé kò sí ìkankan lára àwọn ará wa tó kú.
Ilé ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rin àti igba ó dín márùn-ún (195) ilé àwọn ará wa ló bà jẹ́ gan-an. Ilé ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́sàn-án (9) àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé mọ́kànléláàádọ́ta (351) ilé àwọn ará ló sì bà jẹ́ díẹ̀. Torí pé ó léwu gan-an láti wà nínú ilé, inú àgọ́ lọ̀pọ̀ àwọn ará lọ forí pa mọ́ sí.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Philippines ti yan Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù méjì láti bójú tó iṣẹ́ ìrànwọ́ náà. Àwọn mẹ́fà tó jẹ́ aṣojú láti ẹ̀ka ọ́fíìsì tí mẹ́ta lára wọn wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ti ṣèbẹ̀wò sí agbègbè náà kí wọ́n lè pèsè ìtùnú àti ìṣírí nípa tẹ̀mí.
A gbàdúrà pé kí Jèhófà máa ran àwọn ará tí àjálù bá yìí lọ́wọ́.—Sáàmù 70:5.