JANUARY 20, 2020
PHILIPPINES
Ó Ṣeé Ṣe Kí Òkè Ayọnáyèéfín Tó Wà Lórílẹ̀-Èdè Philippines Bú Gbàù
Ní January 12, 2020, òkè ayọnáyèéfín tó ń jẹ́ Taal ní ìlú Batangas lórílẹ̀-èdè Philippines tú eérú gbígbóná jáde. Eérú gbígbóná náà rìn jìnnà sókè nínú òfúrufú gan-an, kódà ó fẹ́ẹ̀ tó òpó iná kan àtààbọ̀ tó fi lọ sókè. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ló mú káwọn aláṣẹ kìlọ̀ pé ìgbàkigbà ni òkè yìí lè “bú gbàù, ó sì lè ṣe àwọn èèyàn léṣe.” Torí pé òkè Taal yìí ló burú jù lára àwọn òkè tó sábà máa ń bú gbàù ní orílẹ̀-èdè náà, ìjọba ti pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn tó ń gbé lágbègbè tí òkè náà wà kúrò níbẹ̀ pátápátá.
Títí di àkókò yìí, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ló ti kó kúrò lágbègbè yẹn tí wọ́n sì lọ síbi tí kò séwu. Àwọn kan lára wọn ń gbénú Gbọ̀ngàn Ìjọba nígbà táwọn míì ń gbé lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí míì. Ìròyìn fi hàn pé kò sí ìkankan nínú àwọn ará wa tó fara pa. Kára lè tu àwọn ará wa yìí, Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ti yan Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣèrànwọ́ Nígbà Àjálù láti bójú tó ohun táwọn ará tó kúrò nílé wọn máa nílò.
Àdúrà wa ni pé kí ìgbàgbọ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lórílẹ̀-èdè Philippines lágbára sí i, kó sì túbọ̀ dá wọn lójú pé Jèhófà ni Ọlọ́run “ààbò wa àti okun wa.”—Sáàmù 46:1-3.