Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ilé àwọn ará wa tí iná jó kanlẹ̀ ní ìlú Taguig City lágbègbè Metro Manila

MAY 21, 2019
PHILIPPINES

Iná Ńlá Tó Sọ ní Philippines Jó Ọ̀pọ̀ Ilé

Iná Ńlá Tó Sọ ní Philippines Jó Ọ̀pọ̀ Ilé

Ní March 2019, iná ńlá kan sọ ní ìlú Calbayog City ní erékùṣù Samar Island lórílẹ̀-èdè Philippines, ó sì jó ilé méjìdínláàádóje (128). Lóṣù kan sáájú àkókò yẹn, iná sọ láwọn ibì kan ní ìlú Taguig City tó wà ní erékùṣù Luzon. Lápapọ̀, ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méje ni iná náà jó. Ọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí míì tí iná náà ò dé làwọn ará wa yìí ń gbé báyìí.

Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣètò tó yẹ, wọ́n sì pèsè oúnjẹ, omi àti aṣọ fáwọn tọ́rọ̀ kàn. Àwọn alàgbà tó wà lágbègbè náà ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ará tí àjálù yìí kàn, wọ́n sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Ìgbìmọ̀ méjì tó ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ ti ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa tún ilé àwọn ará wa tó bà jẹ́ kọ́.

Ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní yé jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ará wa tí àjálù iná yìí ṣẹlẹ̀ sí.—Sáàmù 62:8.