SEPTEMBER 11, 2019
PHILIPPINES
Omíyalé Ṣọṣẹ́ Lórílẹ̀-Èdè Philippines
Ní August 28, 2019, àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò kan mú kí odò Talomo kún àkúnya, omi náà sí ya wọ ìlú Davao. Ìròyìn látọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ fi hàn pé omíyalé tó tẹ̀ lé òjò yìí lé ìdílé tó tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti márùndínláàádọ́ta (545) kúrò nílé wọn.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì Philippines ròyìn pé ọgọ́fà (120) akéde látì ìjọ márùn-ún ni àkúnya omi yìí ṣàkóbá fún. Ọ̀pọ̀ àwọn akéde yìí ló fara pa mọ́ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àkúnya omi náà wó ilé mẹ́ta, ó sì ba ilé mẹ́rin tó jẹ́ ti àwọn ará wa jẹ́.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì gbé Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù dìde láti bójú tó àìní àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣàkóbá fún. Ìgbìmọ̀ yìí rí i dájú pé àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣàkóbá fún rí àwọn ohun tí wọ́n nílò, wọ́n sì ṣètò láti ṣé ìmọ́tótó àwọn ilé tí omi ya wọ̀.
Àdúrà wa ni pé kí ìfẹ́ táwọn ará ń fi hàn máa tu àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nílùú Davao nínú, pàápàá ní àkókò tó le koko yìí.—Róòmù 12:10.