Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 23, 2017
PHILIPPINES

Iná Sọ Àwọn Ilé Di Eérú ní Philippines

Iná Sọ Àwọn Ilé Di Eérú ní Philippines

Ní August 5, 2017, iná sọ ní àgbègbè Agdao nílùú Davao tó wà ní etíkun erékùṣù Mindanao, ní gúúsù orílẹ̀-èdè Philippines.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan tí iná yìí pa, ilé àwọn ìdílé mẹ́tàlá [13] ni iná náà ṣe báṣubàṣu, ó sì sọ àwọn mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [29] tó ń gbé àwọn ilé náà di aláìnílélórí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti gba àwọn ará wọn tí iná yìí sọ di aláìnílé sílé. Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Manila ti yan ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù láti bójú tó bí wọ́n á ṣe pín àwọn nǹkan tó wà fún ìrànwọ́.

Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń bójú tó iṣẹ́ ìrànwọ́ nígbà àjálù láti oríléeṣẹ́ wọn, owó táwọn èèyàn fi ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ni wọ́n sì ń lò.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Philippines: Dean Jacek, +63-2-224-4444