Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 1, 2016
PHILIPPINES

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣètò Bí Wọ́n Á Ṣe Ṣèrànwọ́ Nígbà Ìjì Líle Tó Jà Léraléra ní Philippines

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣètò Bí Wọ́n Á Ṣe Ṣèrànwọ́ Nígbà Ìjì Líle Tó Jà Léraléra ní Philippines

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ran àwọn ará wọn àtàwọn míì tí àjálù dé bá lọ́wọ́ nígbà tí ìjì líle tí wọ́n ń pè ní Typhoon Sarika (táwọn aráàlú mọ̀ sí Karen) jà ní October 16, 2016, tí ìjì Typhoon Haima (táwọn aráàlú mọ̀ sí Lawin) sì jà ní October 19, 2016. Ìjì yẹn ṣọṣẹ́ gan-an ní erékùṣù Luzon, lápá àríwá orílẹ̀-ède Philippines. Ìjì Typhoon Haima yẹn le gan-an, òun ni ìjì tó le jù tó tíì ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Philippines látìgbà tí ìjì Super Typhoon Haiyan (táwọn aráàlú mọ̀ sí Yolanda) tó gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn ti jà lọ́dún 2013.

Ìkankan nínú ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000] àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Philippines ò kú, wọn ò sì fara pa yánnayànna nígbà àjálù tó wáyé yìí. Àmọ́ ìròyìn tá a kọ́kọ́ gbọ́ fi hàn pé atẹ́gùn líle tó fẹ́, omi tó yalé àtàwọn òkè tó ya nígbà tí ìjì Typhoon Haima jà ba àwọn ilé wọn àti Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn jẹ́. Ó kéré tán, ẹgbẹ̀rún kan ó lé méjìdínlọ́gọ́ta [1,058] ni ilé wọn tó bà jẹ́, Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ibi ìjọsìn wọn mẹ́tàlélógójì [43] ló sì bà jẹ́.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Philippines ti ṣètò ìgbìmọ̀ tó ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù sílùú Tuguegarao, ní erékùṣù Luzon, wọ́n sì ń fi àwọn nǹkan bí oúnjẹ àti omi tó ṣeé mu ránṣẹ́ síbẹ̀. Títí di báyìí, ọkọ̀ akẹ́rù mẹ́jọ ni wọ́n ti fi kó nǹkan lọ sí àwọn ibi tí àjálù náà ti ṣẹlẹ̀. Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé táwọn èèyàn lè máa gbé fúngbà díẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń tún àwọn ilé tó ti bà jẹ́ àtàwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe.

Láti oríléeṣẹ́ wa ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣètò bá a ṣe ń ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá, wọ́n ń lo owó táwọn èèyàn fi ń ṣètọrẹ fún iṣẹ́ ìwàásù táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-718-560-5000

Philippines: Dean Jacek, 63-2-224-4444