Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JANUARY 21, 2015
PHILIPPINES

Lẹ́yìn Ọdún Kan Tí Ìjì Líle Jà ní Ìlú Haiyan, Àwọn Tí Ìjì Ba Ilé Wọn Jé Rílé Tuntun Kó Sí

Lẹ́yìn Ọdún Kan Tí Ìjì Líle Jà ní Ìlú Haiyan, Àwọn Tí Ìjì Ba Ilé Wọn Jé Rílé Tuntun Kó Sí

Ìlú MANILA, lórílẹ̀-èdè Philippines—Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé ní pẹrẹu lẹ́yìn ìjì líle tó ṣẹlẹ̀ ní ìlú Haiyan. Wọ́n tún ilé tó tó ọgọ́rùn-ún méje àtààbọ̀ [750] kọ́, wọ́n sì tún àwọn ilé míì ṣe láàárín ọdún kan yẹn.

Ó kéré tán, àwọn márùn ún tó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ ìkọ́lé lè tún ilé kan kọ́ láàárín ọjọ́ márùn ún.

Arákùnrin Dean Jacek, tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Philippines sọ pé: “Ohun tó wà lọ́kàn wa ni pé ká parí gbogbo iṣẹ́ ìkọ́lé yẹn ní oṣù September ọdún2014. Àmọ́ nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yẹn, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó yọ̀ǹda ara wọn, a parí iṣẹ́ ìkọ́lé náà kí oṣù August tó parí.”

Ọ̀pọ̀ àwọn ará lórílẹ̀-èdè yẹn àti láti ilẹ̀ òkèèrè ló lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ àtúnkọ́ náà.

Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi owó táwọn ará dá kárí ayé ránṣẹ́ sí àwọn tó ń bójú tó ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn tí jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí. Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Manila ṣètò ìgbìmọ̀ tó máa bójú tó ṣíṣe àtúnkọ́ láwọn àgbègbè tó bàjẹ́. Iṣé yìí ní nínú ṣíṣàtúnṣe àti ṣíṣe àtúnkọ́ àwọn ilé mẹ́tàdínláàádọ́sàn-án [167] ní àdúgbò Tacloban, ọgọ́rùn-ún méjì lé ní àádọ́ta àti mẹ́fà [256] ilé ní àgbègbè Ormoc, ilé mọ́kànlélọ́gọ́rùn-ún [101] ní àdúgbò Cebu, àti igba ó lé méjìdínlógún [218] ilé ní àyíká Roxas. Àwọn ará tí iye wọ́n jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé méjìlélógún [522] láti ìlú Philippines ló yọ̀ǹda ara wọn, pẹ̀lú àwọn àádọ́rùn-ún [90] míì láti ìlú mìíràn ló kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́lé yìí.

Ọ̀gbẹ́ni Ferdinand Martin G. Romualdez, tó ń ṣojú fún ìlú Leyte àkọ́kọ́.

Ọ̀gbẹ́ni Ferdinand Martin G. Romualdez, tó ń ṣojú fún ìlú Leyte àkọ́kọ́, ṣàkíyèsí pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ni àjọ tí kò sí lábẹ́ ìjọba tó kọ́kọ́ lo ìdánúṣe láti ṣe àtúnkọ́ àwọn ilé tó bàjẹ́. . . . A ò le dúpẹ́ oore tí ẹ ṣe fún ìdílé mi tán àti àwọn èèyàn wa.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: J. R. Brown, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tẹlifóònù +1 718 560 5000

Philippines: Dean Jacek, tel. +63 2 411 6090