Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 12, 2018
PHILIPPINES

Ìjì Líle Yutu Tún Ṣọṣẹ́, Ó Jà ní Philippines

Ìjì Líle Yutu Tún Ṣọṣẹ́, Ó Jà ní Philippines

Ìjì Líle Yutu tó ṣọṣẹ́ gan-an ní Àwọn Erékùṣù Northern Mariana ní October 24 tún jà ní erékùṣù Luzon ní Tuesday, October 30. Erékùṣù yìí ló tóbi jù lórílẹ̀-èdè Philippines. Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá tó bá ìjì yẹn rìn fa omíyalé, ó mú kí ilẹ̀ ya, èyí sì pa àwọn èèyàn. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni wọ́n kó kúrò lágbègbè náà, èèyàn mọ́kànlá (11) ló sì kú.

Ìròyìn tá a gbọ́ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Philippines ni pé kò sí ìkankan lára àwọn ará wa tí ìjì náà pa tàbí tó ṣe léṣe. Àmọ́ ilé mẹ́tàléláàádọ́rin (73) tó jẹ́ ti àwọn ará wa ló bà jẹ́, títí kan Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́fà. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Philippines ti ń ṣètò ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù náà ṣẹlẹ̀ sí.

A ò dákẹ́ àdúrà lórí àwọn ará wa ní Philippines, torí ó ti di ìjì líle méjìdínlógún (18) báyìí tó jà níbẹ̀ lọ́dún yìí. Bí wọ́n ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà làwa náà gbẹ́kẹ̀ lé e, a sì mọ̀ pé ó máa gbé wa ró.—Sáàmù 55:22.