Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JANUARY 21, 2015
POLAND

Àwọn Tí Kò Kú sí Àgọ́ Auschwitz Ṣé Ayẹyẹ Àádọ́rin Ọdún Tí Wọ́n ti Wà Lómìnira, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Wà Lára Àwọn Tí Wọ́n Rántí

Àwọn Tí Kò Kú sí Àgọ́ Auschwitz Ṣé Ayẹyẹ Àádọ́rin Ọdún Tí Wọ́n ti Wà Lómìnira, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Wà Lára Àwọn Tí Wọ́n Rántí

WARSAW, Poland—Tó bá di January 27, 2015, ọ̀pọ̀ èèyàn máa pé jọ láti ṣayẹyẹ àádọ́rin ọdún tí wọ́n dá àwọn èèyàn sílẹ̀ lómìnira ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Auschwitz. Ìjọba Násì ti ilẹ̀ Jámánì ìgbàanì ló kọ́ àgọ́ yìí. Àgọ́ yìí ni wọ́n ti máa ń pa àwọn ẹ̀yà tí ìjọba Násì kórìíra. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti onírúurú orílẹ̀-èdè títí kan àwọn tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Jámánì pàápàá ni wọ́n fìyà jẹ níbẹ̀.

Àwọn tó ṣètò ayẹyẹ yìí ni àjọ International Auschwitz Council àtàwọn tó ń bójú tó Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí ti ìpínlẹ̀ Auschwitz-Birkenau. Wọ́n retí pé kí ààrẹ orílẹ̀-èdè Poland ìyẹn Bronisław Komorowski wá síbi ayẹyẹ náà. Bákan náà, àwọn aṣojú láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè máa wà níbẹ̀. Wọ́n máa gbé ètò yìí sáfẹ́fẹ́ lórí íńtánẹ́ẹ̀tì.

Àgọ́ Auschwitz wà ní agbègbè Oświęcim, ìyẹn ìlú kan lórílẹ̀-èdè Poland tí ìjọba Násì gbà nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Àgọ́ ìfìyàjẹni làwọn ọmọ ilẹ̀ Jámánì kọ́kọ́ fi Auschwitz ṣe. Nígbà yẹn, wọ́n kó ọgọ́rùn-ún méje [700] àwọn ẹlẹ́wọ̀n láti Poland wá síbẹ̀ ní June 1940. Àmọ́ kò pé tí wọ́n fi mú àgọ́ náà gbòòrò sí i, wọ́n kọ́ ogójì àgọ́ ńlá síbẹ̀ àtàwọn àgọ́ kéékèèké míì. Ilé gáàsì mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n kọ́ sí Auschwitz-Birkenau máa ń pa ọ̀kẹ́ kan [20,000] èèyàn lójúmọ́. Ó kéré tan, ó lé ní mílíọ̀nù kan èèyàn àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní irinwó [400] tí wọ́n kó lọ sí àgọ́ Auschwitz láàárín ọdún márùn-ún tí wọ́n fi lò ó.

Ní ìkànnì Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí ti ìpínlẹ̀ Auschwitz-Birkenau, wọ́n sọ pé: “Ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni ìwé tó sọ nípa ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Àgọ́ Ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Auschwitz sọ̀rọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà (tí wọ́n mọ̀ sí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú àgọ́ náà) tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí ìgbàgbọ́ wọn. Ó yẹ kí wọ́n túbọ̀ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n yìí láfiyèsí torí pé wọn ò yẹhùn lórí ìgbàgbọ́ wọn láìka bí ìyà ṣe jẹ wọ́n tó nínú àgọ́ náà.” Àkọsílẹ̀ tó wà níbi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí náà fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n kọ́kọ́ kó lọ sí àgọ́ Auschwitz. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí ni wọ́n kó lọ, ohun tó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá mẹ́rin nínú mẹ́wàá nínú wọn ló kú síbẹ̀.

Andrzej Szalbot (Nọ́ńbà ẹlẹ́wọ̀n–IBV 108703): Ìjọba Násì mú un lọ́dún 1943, wọ́n sì rán an lọ sí àgọ́ Auschwitz torí ó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun.

Láti ọdún 1933 ni ìjọba Násì ti dìídì dájú sọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì fòfin de iṣẹ́ wọn jákèjádò ilẹ̀ Jámánì. Ìlànà Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí náà ń tẹ̀ lé kò bá ohun tí ìjọba Násì fẹ́ mu. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Ẹlẹ́rìí náà kì í bá wọn dáṣà kan tí ìjọba mú lọ́ranyàn pé káwọn èèyàn máa ṣe, ìyẹn kí wọ́n máa sọ pé, “Ẹ Kókìkí Hitler!” Wọ́n ka irú àṣà bẹ́ẹ̀ sí jíjọ́sìn Hitler dípò jíjọ́sìn Ọlọ́run. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ò tún bá wọn lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ ológun, èyí mú kí ìjọba kà wọ́n sí ọlọ̀tẹ̀. Wọ́n fàṣe ọba mú Andrzej Szalbot lọ́dún 1943, wọ́n sì rán an lọ sí àgọ́ Auschwitz lẹ́ni ọdún mọ́kàndínlógún [19], Andrzej sọ pé: “Tó o bá kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun, àgọ́ ìfìyàjẹni lò ń lọ nìyẹn.” Wọ́n ṣèlérí fáwọn Ẹlẹ́rìí náà pé àwọn máa dá wọn sílẹ̀ lómìnira tí wọ́n bá buwọ́ lu ìwé pé àwọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ àti pé àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn náà kò tọ̀nà. Andrzej Szalbot kọ̀ láti buwọ́ lu ìwé yìí.

Wọ́n sọ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé àwọn máa dá wọn sílẹ̀ lómìnira tí wọ́n bá sọ pé àwọn kò ṣe ẹ̀sìn náà mọ́ nípa bíbuwọ́ lu fọ́ọ̀mù kan tó jọ èyí.

Àwọn ìwé àkọsílẹ̀ ìjọba Násì máa ń lo ìkékúrú náà “IBV,” tí wọ́n bá ń tọ́ka sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìkékúrú yìí dúró fún Internationale Bibelforscher-Vereinigung (Ẹgbẹ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kárí Ayé), ìyẹn orúkọ tí wọ́n mọ̀ wọ́n sí nílẹ̀ Jámánì. Ìjọba Násì fún àwọn Ẹlẹ́rìí ní aṣọ ẹ̀wọ̀n tó ní àmì onígun mẹ́ta aláwọ̀ àlùkò. Àmì yìí máa ń mú káwọn Ẹlẹ́rìí dá ara wọn mọ̀ nínú àgọ́ náà. Wọ́n máa ń pàdé ní gbogbo ìrọ̀lẹ́ kí wọ́n tó pè wọ́n jáde kí wọ́n lè fún ara wọn níṣìírí. Wọ́n sì máa ń pàdé ní bòókẹ́lẹ́ kí wọ́n lè jíròrò Bíbélì pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́wọ̀n míì tó nífẹ̀ẹ́ sí inú rere àti ìgbàgbọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí náà. Èyí mú káwọn ẹlẹ́wọ̀n kan di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú àgọ́ Auschwitz.

Ni àárọ̀ Saturday, January 27 ọdún 1945, àwọn ọmọ ogun ìlú Soviet Union dé sí agbègbè Oświęcim. Nígbà tó fi máa di aago mẹ́ta ọ̀sán, àwọn ọmọ ogun yìí ti dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ó tó ẹgbẹ̀rún méje [7,000] sílẹ̀ ní àwọn àgọ́ Auschwitz Kìíní, Auschwitz Kejì (Birkenau), àti Auschwitz Kẹta (Monowitz).

Stanisław Zając dé àgọ́ Auschwitz ní February 16, 1943.

Stanisław Zając tó jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n mú lọ́ranyàn kúrò ní àgọ́ Auschwitz nígbà táwọn ọmọ ogun ìlú Soviet Union sún mọ́ tòsí. Stanisław Zając pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọgọ́rùn-ún méjì [3,200] àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kúrò ní àgọ́ kékeré kan tó ń jẹ́ Jaworzno. Wọ́n mú wọn rìnrìn àjò ikú la agbègbè tí yìnyín bò kanlẹ̀. Ọjọ́ mẹ́ta gbáko ni wọ́n fi rìnrìn náà títí dé Blechhammer, ìyẹn àgọ́ kékeré kan tó wà nínú igbó. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ nínú àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà ló kú sọ́nà. Stanisław Zając ròyìn ìjà tó wáyé nígbà tóun àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù fara pamọ́ sínú àgọ́ náà, ó ní: “À ń gbúròó àwọn ọkọ̀ ogun tó ń kọjá àmọ́ kò sẹ́ni tó láyà tó láti lọ wo àwọn ọmọ ogun tó ni ín. Ìgbà tó dàárọ̀ la tó mọ̀ pé tàwọn ọmọ ogun ìlú Soviet Union ni. . . . Àwọn ọmọ ogun ìlú Soviet Union ti kún inú igbó náà, ọjọ́ yẹn ni mo bọ́ nínú àgọ́ ìfìyàjẹni tí mo wà.”

Tó bá di January 27 ọdún yìí, ọ̀pọ̀ àwọn ètò tó tan mọ́ ayẹyẹ àádọ́rin ọdún táwọn èèyàn gba òmìnira ní àgọ́ Auschwitz ni wọ́n máa ṣe ni ọ̀pọ̀ ìlú kárí ayé.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: J. R. Brown, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tẹlifóònù +1 718 560 5000

Jámánì: Wolfram Slupina, tẹlifóònù +49 6483 41 3110

Poland: Ryszard Jabłoński, tẹlifóònù +48 608 555 097