NOVEMBER 3, 2017
PORTUGAL
Iná Tó Tíì Pààyàn Jù Lọ ní Portugal
Ojú ọjọ́ tó ń gbóná kọjá sísọ àti ọ̀gbẹlẹ̀ tó lágbára ti yọrí sí iná lórílẹ̀-èdè Portugal, tọ̀tẹ̀ yìí ló sì tíì pààyàn jù lórílẹ̀-èdè náà. Lóṣù June, èèyàn mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [64] ló kú, èèyàn márùndínláàádọ́ta [45] ló sì kú lóṣù October. Ní àárín oṣù October, ìgbà ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé mẹ́tàlélógún [523] ni iná ṣẹ́ yọ. Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Pàjáwìrì lábẹ́ ìdarí Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù sọ pé, lọ́dún yìí, ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù kan ààbọ̀ eékà ilẹ̀ tí iná ti jó, ó fi ìlọ́po mẹ́fà ju iye ilẹ̀ tó sábà máa ń jóná lórílẹ̀-èdè náà tẹ́lẹ̀, ìyẹn ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ó lé márùn-ún [205,000] eékà ilẹ̀
Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Portugal ròyìn pé iná náà gbẹ̀mí ọ̀kan nínú àwọn ará wa àti ìbátan rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́rin. Iná ọ̀hún tún ba ilé àwọn ará wa kan jẹ́, ó tiẹ̀ ba àwọn kan jẹ́ kọjá àtúnṣe, títí kan ilẹ̀ oko wọn àtàwọn irinṣẹ́ wọn, kódà, ó pa lára ẹran ọ̀sìn wọn. Àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin ti ń ṣiṣẹ́ kára láti ran ara wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè palẹ̀ àwọn ohun tí iná jó mọ́, kí wọ́n sì gbé àwọn igi tó ti jóná àtàwọn ìdọ̀tí míì kúrò.
A ṣètò Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù sí àgbègbè náà kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí. Bákan náà, méjì lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lórílẹ̀-èdè Portugal dara pọ̀ mọ́ àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà ìjọ láti máa bẹ àwọn ará wa lọ́kùnrin lóbìnrin wò kí wọ́n lè fún wọn níṣìírí.
Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà túbọ̀ jẹ́ ká máa fìfẹ́ ti àwọn ará wa ní Portugal lẹ́yìn, kó sì máa tù wọ́n nínú kí wọ́n lè bọ́ nínú ìṣòro tí iná ọ̀gbálẹ̀-gbáràwé yìí dá sílẹ̀.—Sáàmù 71:21.
Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:
Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000
Portugal: João Pedro Candeias, +351-214-604-339