Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 21, 2017
PUERTO RICO

Ìròyìn Tá a kọ́kọ́ gbọ́ nípa ìjì ńlá kan tí wọ́n pè ní Hurricane Maria

Ìròyìn Tá a kọ́kọ́ gbọ́ nípa ìjì ńlá kan tí wọ́n pè ní Hurricane Maria

Ní Wednesday, September 20, 2017, ìjì ńlá kan tí wọ́n pè ní Hurricane Maria jà, ó sì bá nǹkan jẹ́ gan-an ní Puerto Rico. Èyí ni ìjì karùn-ún tó lágbára jù lọ nínú èyí tó tíì jà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, kò sí iná mọ̀nàmọ́ná ní gbogbo erékùṣù náà, ìjọba sì ti ṣòfin pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ rìn níta láti aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́.

Àwọn ará wa kankan kò fara pa. A sì ti ń ṣètò láti pèsè ìrànwọ́ fún wọn. Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tí kò bà jẹ́ la máa gbé, ibẹ̀ náà làá ti máa pín àwọn ohun ìrànwọ́ fáwọn èèyàn.

Ìjì náà ba apá kékeré kan jẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní ìlú San Juan. Àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì wà ní àláàfíà, kò sí ẹnì kankan tó fara pa. Àmọ́ íńtánẹ́ẹ̀tì ti bà jẹ́, jẹnẹrátọ̀ ni wọ́n sì ń lò.

Ó dájú pé àwọn ará wa ń rí ìtùnú gbà bí wọ́n ṣe rí iṣẹ́ ribiribi tí ètò Jèhófà ń ṣe láti pèsè ìrànwọ́ fún wọn.—2 Kọ́ríńtì 1:3

Media Contact:

International: David A. Semonian, Office of Public Information, +1-845-524-3000