SEPTEMBER 25, 2017
PUERTO RICO
Ìròyìn láti Puerto Rico Lẹ́yìn ìjì líle Hurricane Maria
Ní September 25, 2017, ohun tá a gbọ́ látẹnu àwọn alábòójútó àyíká mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] lára àwọn alábòójútó àyíká mọ́kàndínlógún [19] tó wà nílùú Puerto Rico ni pé arákùnrin wa kan ṣoṣo ló fara pa nígbà tí ìjì líle Hurricane Maria ṣọṣẹ́. A ò tíì rí àwọn alábòójútó àyíká mẹ́rin tó kù tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oorùn ìlú náà bá sọ̀rọ̀ láti mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí níbẹ̀. Àwọn arákùnrin wa tó wà láwọn àyíká tó wà nítòsí ti lọ wá àwọn ọ̀kadà àtàwọn ọkọ̀ tó rọ́kú, kí wọ́n lè fi rìnrìn-àjò lọ wo àwọn ara wa tó wà ní ìwọ̀ oòrùn ìlú náà.
A ó máa bá a nìṣó láti gbàdúrà fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ọ̀wọ́n yìí.—Jákọ́bù 5:16.
Agbenusọ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:
David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000