Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JULY 20, 2020
ROMANIA

Ètò Ìrànwọ́ Ṣe Àwọn Ará Wa Láǹfààní ní Ròmáníà, Baálẹ̀ Ìlú Kan sì Gbóríyìn fún Wọn

Ètò Ìrànwọ́ Ṣe Àwọn Ará Wa Láǹfààní ní Ròmáníà, Baálẹ̀ Ìlú Kan sì Gbóríyìn fún Wọn

Ní June 2020, òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá fa omíyalé nílùú Rodna ní Transylvania, lórílẹ̀-èdè Ròmáníà. Ilé àwọn ará wa mẹ́fà ló bà jẹ́. Ní June 27, 2020, alábòójútó àyíká tó ń bẹ àwọn ará wò nílùú Rodna àtàwọn alàgbà ṣètò pé kí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin márùndínlọ́gbọ̀n (25) láti ìjọ mẹ́ta pèsè ìrànwọ́ pàjáwìrì fáwọn ará tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí. * Baálẹ̀ ìlú Rodna kíyè sí ètò ìrànwọ́ táwọn ará wa ṣe, ó sì yìn wọ́n nínú ètò kan táwọn oníròyìn gbé sáfẹ́fẹ́.

Àárín àfonífojì kan ni ìlú Rodna wà, odò sì pọ̀ níbẹ̀. Ọ̀gbàrá yẹn kó ọ̀pọ̀ ẹrẹ̀ àti ìdọ̀tí dí ojú ọ̀nà, ó sì jẹ́ kó nira gan-an láti wọnú ìlú náà. Ilé ọ̀kan lára àwọn arábìnrin wa wà ní àdúgbò kan tí ẹrẹ̀ àti ìdọ̀tí ti dí ojú ọ̀nà. Ó ṣòro gan-an fún baálẹ̀ àtàwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ láti la ọ̀nà yẹn. Àmọ́ nígbà táwọn ará wa dé, wọ́n kó ìdọ̀tí àti ẹrẹ̀ náà kúrò kí wọ́n lè ráyè bá arábìnrin wa tún ilé rẹ̀ ṣe. Ohun tí wọ́n ṣe yẹn mú kí iṣẹ́ ìrànwọ́ táwọn aláṣẹ ń ṣe túbọ̀ rọrùn.

Nígbà tí iléeṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan ń fọ̀rọ̀ wá baálẹ̀ náà lẹ́nu wò, baálẹ̀ náà gbóríyìn fáwọn ará. Ó ní: “Ohun kan ṣẹlẹ̀ tí mo fẹ́ sọ. Ó jọ mí lójú gan-an. . . . Lọ́jọ́ tá a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe, ọkọ̀ ńlá méjì la fi ń kó ẹrẹ̀ àti ìdọ̀tí, àmọ́ a ò lè parí ẹ̀ lọ́jọ́ yẹn torí pé omíyalé yẹn ba nǹkan jẹ́ gan-an. Lọ́jọ́ kejì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ọgbọ̀n (30) wá ràn wá lọ́wọ́ . . . Nígbà tó fi máa di ìrọ̀lẹ́, a ti parí iṣẹ́ náà.” Ó wá sọ pé: “Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn èèyàn yẹn tó ràn wá lọ́wọ́ láti tún àdúgbò náà ṣe. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo wọn o!”

Baálẹ̀ yẹn tún gbé ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ yìí sórí ìkànnì kan láti fi kí àwọn ará wa. Ó sọ pé: “Kí Jèhófà bù kún gbogbo yín. Ẹ̀ẹ́ pẹ́ láyé o, àjíǹde ara á máa jẹ́, ẹ̀ẹ́ sì máa ṣàṣeyọrí!”

Ohun tó ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Ròmáníà yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé ìwà rere wa máa ń mú ìyìn bá Jèhófà, Baba wa ọ̀run.​—1 Pétérù 2:12.

^ ìpínrọ̀ 2 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lára iṣẹ́ àtúnṣe tá à ń ṣe ti dáwọ́ dúró torí àjàkálẹ̀ àrùn tó wà lóde, àwọn ilé yìí ṣì nílò àtúnṣe ní kíákíá.