APRIL 20, 2021
ROMANIA
Ìrántí Ikú Kristi Ọdún 2021—Àsọyé Ìrántí Ikú Kristi Tí Wọ́n Sọ fún Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì Lórílẹ̀-Èdè Ròmáníà
Láti bí ọdún mẹ́tàdínlógún (17) báyìí làwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Ròmáníà ti ń ṣèpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú àwọn tó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Jilava Bucharest. Àmọ́ nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà bẹ̀rẹ̀, wọn ò lè ṣèpàdè lójúkojú mọ́. Ní ọ̀sẹ̀ méjì ṣáájú Ìrántí Ìkú Kristi tá a ṣe ní March 27, 2021, àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn fọwọ́ sí i pé wọ́n lè máa ṣe ìpàdé wọn látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Torí náà, àwọn ará yẹn bèèrè bóyá àwọn lè ṣe Ìrántí ikú Kristi látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì, àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn sì fọwọ́ sí i. Lápapọ̀, àwọn ẹlẹ́wọ̀n mọ́kànlélógún (21) àti àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n mẹ́rin ló wá síbi Ìrántí Ikú Kristi náà.
Arákùnrin Corneliu Cepan ló sọ àsọyé lọ́jọ́ yẹn ní èdè Ròmáníà. Arákùnrin Angelos Karamplias sì ń tú u sí èdè Gíríìkì fún ọ̀kan lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí kò gbọ́ èdè Ròmáníà. Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ mẹ́rin tó wá síbi Ìrántí Ìkú Kristi lọ́jọ́ náà jẹ́ igbá kejì ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn? Ìyẹn wúni lórí gan-an!
Arákùnrin Cepan sọ pé: “Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé mo sọ àsọyé yìí. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa, wọ́n sì ronú lórí àǹfààní tí ẹbọ ìràpadà Jésù ṣe fún wọn.”
Arákùnrin Karamplias sọ pé: “Inú wa dùn gan-an pé Jèhófà jẹ́ ká lè wàásù fáwọn ẹlẹ́wọ̀n náà ká sì tún sọ àsọyé Ìrántí Ikú Kristi fún wọn. Àdúrà wa ni pé lọ́jọ́ iwájú, káwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù dara pọ̀ mọ́ wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ká lè jọ gbádùn ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì.”
Inú wa dùn pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà èwọ̀n yẹn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà ní àǹfààní láti gbọ́ àsọyé Ìrántí Ikú Kristi látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì.—1 Ti 2:3, 4.