Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn ọmọ iléèwé yìí, àwọn ni wọn ò kọ́kọ́ fún ní káàdì èsì ìdánwò wọn torí pé wọn ò san owó orí tí ṣọ́ọ̀ṣì ń gbà

JUNE 9, 2016
RÙWÁŃDÀ

Ìjọba Orílẹ̀-èdè Rùwáńdà Gbé Ìgbésẹ̀ Láti Fòpin sí Ẹ̀tanú Ẹ̀sìn Níléèwé

Ìjọba Orílẹ̀-èdè Rùwáńdà Gbé Ìgbésẹ̀ Láti Fòpin sí Ẹ̀tanú Ẹ̀sìn Níléèwé

Ìjọba orílẹ̀-èdè Rùwáńdà gbé ìgbésẹ̀ láti fòpin sí ẹ̀tanú tí wọ́n ń ṣe sí àwọn ọmọ iléèwé torí ẹ̀sìn. Wọ́n pàṣẹ kan tó fi dandan lé e pé kí àwọn aláṣẹ iléèwé má fipá mú àwọn ọmọ iléèwé láti ṣe nǹkan tó ta ko ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Ìròyìn ayọ̀ lèyí jẹ́ fáwọn ọmọ tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣe àwọn ohun kan tí àwọn aláṣẹ iléèwé ní kí wọ́n ṣe.

Ọ̀pọ̀ iléèwé lórílẹ̀-èdè Rùwáńdà ló jẹ́ ti ìjọba, àmọ́ àwọn ẹlẹ́sìn ló ń bójú to wọn. Kò sọ́mọ tí ò lè lọ, ìyẹn sì fi hàn pé onírúurú ẹ̀sìn làwọn ọmọ náà á máa ṣe. Àmọ́ àwọn aláṣẹ iléèwé kan ti fipá mú àwọn ọmọ iléèwé wọn láti máa ṣe ohun tó jẹ mọ́ ẹ̀sìn, ayẹyẹ orílẹ̀-èdè tàbí kí wọ́n ní kí wọ́n san owó orí tí ṣọ́ọ̀ṣì ń gbà. Wọ́n sì ti fìyà jẹ àwọn ọmọ tí ò ṣe nǹkan wọ̀nyẹn torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Mínísítà ìjọba kan tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ níléèwé àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama sọ pé ohun táwọn aláṣẹ kan tó ń bójú tó ilé ẹ̀kọ́ máa ń sọ ni pé: “A ò gbà kí àwọn ọmọ iléèwé wa máa ṣe ìjọsìn tó ta ko ohun tá a gbà gbọ́.”

Òfin tí Ìjọba Gbé Kalẹ̀ Jẹ́ Káwọn Èèyàn Lómìnira Ẹ̀rí Ọkàn

Ìjọba dá sí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n ṣe àwọn òfin tuntun kí wọ́n lè fòpin sí ẹ̀tanú táwọn aláṣẹ ń ṣe sáwọn ọmọ níléèwé torí ẹ̀sìn. Àpilẹ̀kọ 12 nínú Òfin ìjọba No. 290/03, tí wọ́n gbé jáde nínú ìwé ìròyìn Official Gazette ní December 14, 2015, sọ pé àwọn aláṣẹ iléèwé kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ọmọ iléèwé lómìnira láti ṣe ìjọsìn tó bá ẹ̀sìn wọn mu, kí wọ́n sì gbà wọ́n láyè láti máa gbàdúrà bí wọ́n ṣe ń ṣe nínú ẹ̀sìn wọn, níwọ̀n ìgbà tí kò bá ti ṣèdíwọ́ fún ẹ̀kọ́ wọn níléèwé, tí ẹ̀sìn wọn sì ti forúkọ sílẹ̀ lábẹ́ òfin.

Àwọn aláṣẹ iléèwé kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ọmọ iléèwé lómìnira láti ṣe ìjọsìn tó bá ẹ̀sìn wọn mu.—Order No. 290/03, Àpilẹ̀kọ 12

Ohun tí ìjọba ṣe yìí kín ìdájọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Karongi ṣe lẹ́yìn. Ilé Ẹjọ́ yìí dá ẹjọ́ àwọn ọmọ iléèwé kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n lé kúrò níléèwé ní May 2014. Àwọn aláṣẹ iléèwé náà ò gbà nígbà táwọn ọmọ náà sọ pé àwọn ò ní lọ́wọ́ sí ayẹyẹ ìsìn kan tí wọ́n ṣe níléèwé wọn. Ilé ejọ́ dá àwọn ọmọ náà láre, wọ́n sì ní kí wọ́n pa dà síléèwé, kí wọ́n máa bá ẹ̀kọ́ wọn lọ.

Ẹjọ́ míì tún wáyé ní Àgbègbè Ngororero. Ọ̀gá iléèwé kan níbẹ̀ kọ̀ láti fún àwọn ọmọ tí iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n (30) ní káàdì èsì ìdánwò wọn torí pé wọn ò san owó orí tí ṣọ́ọ̀ṣì ń gbà, owó tí ò sí lára owó iléèwé àwọn ọmọ. Nígbà táwọn òbí àwọn ọmọ náà lọ fẹjọ́ sun òṣìṣẹ́ ìjọba tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ lágbègbè yẹn, ṣe ni ara rọ ọ̀gá iléèwé náà, ó sì fún gbogbo àwọn ọmọ ní káàdì èsì ìdánwò wọn nígbà tọ́dún parí.

Ara Tu Àwọn Ọmọ Iléèwé Tí Wọ́n Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Wọ́n lé Chantal Uwimbabazi tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò níléèwé rẹ̀ tó wà ní Àgbègbè Ngororero torí pé kò lọ síbi Ayẹyẹ Ìsìn Kátólíìkì tí wọ́n ṣe níléèwé rẹ̀. Àwọn ọmọ kíláàsì ẹ̀ àtàwọn míì fi ṣe yẹ̀yẹ́ torí ọ̀rọ̀ yìí, odindi ọdún kan sì ni ò fi lè lọ sílé ẹ̀kọ́. Nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ síléèwé míì, àmọ́ ibẹ̀ jìn gan-an sílé wọn, owó tí wọ́n ń san níbẹ̀ sì wọ́n. Bẹ́ẹ̀, bàbá ẹ̀ ti kú, ìyá nìkan ló ń dá gbọ́ bùkátà, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́. Nígbà tí Chantal gbọ́ nípa àwọn òfin tuntun tí ìjọba gbé kalẹ̀, ṣe lara tù ú. Ó sọ pé, “Àwọn ọmọ míì tírú nǹkan yìí ń ṣẹlẹ̀ sí láwọn iléèwé tí àwọn ẹlẹ́sìn ń darí máa wá gbádùn ẹ̀kọ́ wọn, kò sì sẹ́ni tó máa fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n.”

Òfin tuntun yìí bá Òfin Ilẹ̀ Rùwáńdà mu, èyí tó jẹ́ káwọn èèyàn lómìnira ẹ̀sìn, kí wọ́n sì lẹ́tọ̀ọ́ láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ níléèwé. Àwọn ọmọ iléèwé tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn òbí wọn ń wọ̀nà fún ìgbà tí kò ní sí ẹ̀tanú ẹ̀sìn mọ́. Inú wọn ń dùn pé ìjọba ò fọwọ́ lẹ́rán, wọ́n gbé ìgbésẹ̀ láti gbèjà àwọn ọmọ iléèwé kí wọ́n lè máa gbádùn òmìnira ẹ̀sìn tí wọ́n ní.