Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 22, 2017
SIERRA LEONE

Ilẹ̀ Ya, Ó Sì Pa Àwọn Èèyàn ní Siria Lóònù

Ilẹ̀ Ya, Ó Sì Pa Àwọn Èèyàn ní Siria Lóònù

Láàárọ̀ August 14, 2017, àkúnya omi àti ilẹ̀ yíya ba àwọn ṣọ́ọ̀bù, àwọn ojú ọ̀nà àtàwọn ilé jẹ́ nílùú Freetown, tó jẹ́ olú ìlú Siria Lóònù, jàǹbá yìí kọjá sísọ. Ó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] èèyàn tí wọ́n ti rí pé ó kú, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] àwọn míì ni wọn ò sí tíì mọ ibi tí wọ́n wà. Ẹ̀rù ń ba àwọn aláṣẹ pé àwọn òjò míì tí wọ́n ti gbọ́ pé ó máa rọ̀ tún máa fa àjálù kún èyí tó wà nílẹ̀.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Siria Lóònù sọ pé kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan tó kú tàbí tó fara pa nínú àjálù yìí. Àmọ́, ìdílé méjì ni omi gbalé wọn. Àwọn alàgbà ìjọ tó wà lágbègbè náà ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi tiwọn ró. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn alàgbà náà ń sọ ohun táwọn èèyàn lè ṣe láti dáàbò bo ara wọn tí àkúnya omi bá tún ṣẹlẹ̀.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Office of Public Information, +1-845-524-3000

Siria Lóònù: Collin Attick, +232-76-67-90-75