Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 14, 2019
SLOVAKIA

Àpéjọ Àgbègbè Àkọ́kọ́ Tá A Ṣe Ní Èdè Rómánì (Ìlà-Oòrùn Slovakia)

Àpéjọ Àgbègbè Àkọ́kọ́ Tá A Ṣe Ní Èdè Rómánì (Ìlà-Oòrùn Slovakia)

Ọ̀kan lára àwọn mọ́kàndínlógún (19) tó ṣèrìbọmi

Ní July 20 sí 21, 2019, àwọn ará wa ṣe àpéjọ àgbègbè àkọ́kọ́ ní èdè Rómánì ní Slovakia nínú pápá ìṣeré tí wọ́n ń pè ní Winter Stadium ní Michalovce. Ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún méjì àti mẹ́rìndínlọ́gọ́rin (1,276) ló pésẹ̀ sí àpéjọ ọlọ́jọ́ méjì yìí, nígbà tí àwọn mọ́kàndínlógún (19) sì ṣèrìbọmi.

Àwọn ará láti orílẹ̀-èdè mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló pésẹ̀ sí àpéjọ yìí, ìyẹn Belgium, Czech Republic, Great Britain àti Ukraine. Ohun tó wú àwọn tó wá síbẹ̀ lórí jù ni bí wọ́n ṣe wo fíìmù Ìtàn Jòsáyà: Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà; Kórìíra Ohun Búburú, ní èdè ìbílẹ̀ wọn.

November 2014 ni wọ́n dá ìjọ àkọ́kọ́ lédè Rómánì sílẹ̀ ní Slovakia, ọdún márùn-ún péré lẹ́yìn náà ni àpéjọ yìí sì wáyé. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ìjọ mẹ́sàn-án, àwùjọ mẹ́wàá àti àwọn tó fẹ́ di àwùjọ mẹ́rìnlá (14) tó ń sọ èdè Rómánì ni ẹ̀ka ọ́fíìsì Czech-Slovak ń bójú tó.

Peter Tirpak, alábòójútó pápá ìṣeré náà sọ pé: “Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wa wú wa lórí gan-an. Ẹ máa ń dúró lórí ọ̀rọ̀ yín. Inú wa máa dùn tẹ́ ẹ bá tún pa dà wá.”

Peter Varga, tó jẹ́ alábòójútó àpéjọ sọ pé: “Mí ò tíì ṣe irú àpéjọ yìí rí. Mánigbàgbé ni àpéjọ yìí jẹ́ fún àwọn ará wa tó ń sọ èdè Rómánì. Lẹ́yìn orin ìparí, ṣé ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í dì mọ́ra wọn bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò mọ ara wọn rí. Ọ̀pọ̀ ló ń da omijé ayọ̀ lójú.”

A bá àwọn ẹgbẹ̀rún kan àti mẹ́wàá (1,010) akéde tó ń sọ èdè Rómánì ní Slovakia yọ̀. Àpéjọ yìí jẹ́ ká rí ojúlówó ìfẹ́ ará tó wà láàárín àwọn èèyàn Jèhófà.​—Jòhánù 13:34,35.