Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 13, 2019
SOUTH AFRICA

A Mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde ní Èdè Mẹ́ta ní Àpéjọ Àgbáyé Tá A Ṣe Lórílẹ̀-Èdè South Africa

A Mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde ní Èdè Mẹ́ta ní Àpéjọ Àgbáyé Tá A Ṣe Lórílẹ̀-Èdè South Africa

Ní September 6, 2019, a mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde ní èdè Venda, Afrikaans àti Xhosa níbi àpéjọ àgbáyé tá a ṣe nílùú Johannesburg lórílẹ̀-èdè South Africa, ó sì ju mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún (16) èèyàn lọ tó ń sọ àwọn èdè yẹn. Arákùnrin Anthony Morris, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló kéde fáwọn èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì, ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti márùndínláàádọ́rin (36,865) tó kóra jọ sí pápá ìṣeré FNB pé a ti mú Bíbélì náà jáde. Àwọn èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún mọ́kànléláàádọ́ta àti igba ó lé mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (51,229) míì wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà bó ṣe ń lọ lọ́wọ́ ní ibi mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti wọ́n ta àtagbà ètò náà sí, títí kan orílẹ̀-èdè Lesotho, Namibia àti Saint Helena.

Nígbà tí atúmọ̀ èdè kan ń sọ̀rọ̀ lórí ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú Bíbélì náà, ó sọ pé: “Inú wa dùn gan-an pé a lè ka Bíbélì látòkèdélẹ̀ ní èdè tó wọni lọ́kàn!” Atúmọ̀ èdè míì sọ pé: “Ní pàtàkì jùlọ, [Bíbélì tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ mú jáde yìí] máa jẹ́ ká lè sún mọ́ Jèhófà torí pé léraléra ló lo orúkọ Ọlọ́run.”

Bíbélì yìí tún máa ran àwọn ará wa lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá ń wàásù. Ọ̀kan lára àwọn tó túmọ̀ èdè Xhosa sọ pé: “Bíbélì Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe yìí máa ràn wá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn èèyàn máa gbọ́ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni lọ́nà tó ṣe kedere láìsì pé à ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣàlàyé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan.” Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè Afrikaans fi kún un pé: “Ní báyìí, ó ti ṣeé ṣe láti ka Bíbélì kó sì yé ẹ yékéyéké.”

Inú wa dùn pé àwọn ara wa ní Bíbélì tó rọrùn-ún ka, táá sì jẹ́ kí wọ́n sún mọ́ Ọlọ́run wa.​—Jémíìsì 4:8.