South Korea
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní South Korea
-
Iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—106,161
-
Iye àwọn ìjọ—1,252
-
Iye àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi—138,920
-
Iye èèyàn tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan máa wàásù fún—485
-
Iye èèyàn—51,408,000
-
Iye Àwọn Ẹlẹ́rìí Tó Wà Lẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́—0
Àwọn Ará ní South Korea Ní Ìgbàgbọ́ àti Ìgboyà—Wọ́n Kọ̀ Láti Wọṣẹ́ Ológun
Látọdún 1953 ni ìjọba orílẹ̀-èdè Korea ti ń fi àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n torí wọ́n kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Àmọ́, èyí yí pa dà ní February 2019. Kọ́ nípa bí ọ̀rọ̀ ṣe wá dé ibi tó dé yìí.
Ẹnì Kan Tí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kó Ṣiṣẹ́ Ológun Ń Fayọ̀ Retí Ìgbẹ́jọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ
Tó bá di August 30, 2018, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní South Korea máa ṣe àpérò kan lórí ohun tí Ilé Ẹjọ́ Ìjọba sọ pé kí wọ́n ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú míì fún àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.
Ilé Ẹjọ́ Ìjọba South Korea Ṣèpinnu Tá A Ti Ń Retí Tipẹ́—Wọ́n Gbèjà Àwọn Tí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun
Ilé Ẹjọ́ Ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea ṣèpinnu mánigbàgbé kan, wọ́n pàṣẹ fún ìjọba pé tó bá fi máa di ìparí ọdún 2019, kí wọ́n tún Ìlànà Iṣẹ́ Ológun ṣe, kó lè ṣí àyè sílẹ̀ fún iṣẹ́ àṣesìnlú míì.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Pàtẹ Ìwé Tó Dá Lórí Bíbélì Níbi Ìdíje Òlíńpíìkì àti Ìdíje Fáwọn Aláàbọ̀ Ara ti Ọdún 2018
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Korea ṣe àkànṣe ìwàásù láti jẹ́ kí àwọn àlejò tó wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lágbàáyé rí ìwé tó dá lórí Bíbélì gbà lọ́fẹ̀ẹ́ níbi ìdíje Winter Games ti ọdún 2018.