DECEMBER 12, 2019
SOUTH KOREA
Àfihàn Tó Wáyé Ní Ibi Tí Wọ́n Ń Kó Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé Sí Jẹ́ Káráyé Mọ Ohun Tí Wọn Kò Mọ̀ Tẹ́lẹ̀ Nípa Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Korea
Àfihàn kan wáyé níbi tí wọ́n ń kó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí tó ń jẹ́ National Memorial Museum of Forced Mobilization under Japanese Occupation, èyí tó wà nílùú Busan, tó jẹ́ ìlú kejì tó tóbi jù lọ lórílẹ̀ èdè Korea. Níbi àfihàn yìí, wọ́n sọ nípa ohun tí ojú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí nígbà tí orílẹ̀-èdè Japan ń ṣàkóso Korea. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò tiẹ̀ mọ̀ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ rárá. Àfihàn náà bẹ̀rẹ̀ ní November 12, 2019, ó sì máa parí ní December 13, 2019, àkọlé rẹ̀ ni “Bí Ìtàn Ti Ẹ̀ Ń Yí Padà, Ẹ̀rí Ọkàn Wọn Ò Yí Padà.” Àfihàn náà dá lórí bí wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Korea ní ọgọ́rin (80) ọdún sẹ́yìn lábẹ́ àkóso orílẹ̀-èdè Japan àti bí àwọn ará wọ̀nyí ṣe kọ̀ láti dá sí òṣèlú.
Irú àfihàn yìí kọ́kọ́ wáyé ní September 2019 ní gbọ̀ngàn tó ń jẹ́ Seodaemun Prison History Hall * tó wà nílùú Seoul. Èèyàn 51,175 ló wá síbẹ̀ nígbà yẹn, lára wọn sì ni àwọn 5,700 àwọn ará tó wá sí àpéjọ àgbáyé nílùú Seoul.
Ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní Deungdaesa bẹ̀rẹ̀ ní June 1939 sí August 1945, ìgbà yẹn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí i mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn míì tó fẹ́ láti mọ́ òtítọ́ inú Bíbélì tí wọ́n sì ń fi wọ́n sẹ́wọ̀n. Ìjọba fì wọ́n sẹ́wọ̀n torí wọ́n kọ̀ láti jọ́sìn olórí orílẹ̀-èdè àti pé ìjọba gbà pé àwọn ìtẹ̀jáde wa ń kọ́ àwọn èèyàn láti dìtẹ̀ sí ìjọba kí wọ́n má sì lọ sí ojú ogun. Ẹni mẹ́rìndínláàádọ́rin (66) ni àwọn ọlọ́pàá mú, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé iye gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé ni orílẹ̀-èdè Korea nígbà náà nìyẹn. Wọ́n fi ìyà tó le koko jẹ àwọn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n kí wọ́n lè bọ́hùn. Ìyà tí wọ́n fi jẹ wọ́n yìí ló ṣokùnfà àìsàn tó gbẹ̀mí àwọn ará mẹ́fà nínú wọn.
Arákùnrin Hong Dae-il, tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde lórílẹ̀-èdè Korea sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ní orílẹ̀-èdè Korea ni kò mọ̀ pé ó ti lé ní ọgọ́rin (80) ọdún báyìí, ìyẹn lásìkò tí Korea wà lábẹ́ àkóso orílẹ̀-èdè Japan, tí wọ́n ti ń fi ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn dù wọ́n tórí wọ́n kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun àti nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Fún ìgbà àkọ́kọ́, àfihàn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí mú kó ṣeéṣe fún wa láti jẹ́ kí wọ́n gbọ́ nípa ẹ̀.”
Ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ Han Hong-gu, tí òun náà wá síbi àfihàn yìí sọ nípa àwọn tó di ìgbàgbọ́ wọn mú ṣinṣin pé: “Mo gbà pé àpẹẹrẹ rere ni wọ́n fi lélẹ̀ ní ti bó ṣe yẹ kí èèyàn dúró ṣinṣin lórí ohun tó gbà gbọ́, kó mà sì ṣe ohun tó ta ko ẹ̀rí ọkàn rẹ . . . Ní báyìí, tá a ti ń sapá láti gba àwọn èèyàn láyè láti ṣe ohun tó bá ẹ̀rí ọkàn wọn mu, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé ohun tí ojú àwọn Ẹlẹ́rìí ti rí lórí ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn gan-an ló yẹ ká kọ́kọ́ rántí.
Àfihàn yìí gba àfíyèsí àwọn onítàn àtàwọn akọ̀ròyìn, èyí sì ti mú kí ọ̀pọ̀ gbọ́ nípa ìtàn àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọ̀n kò gbà wọ́n láyé láti wọ iṣẹ́ ológun. Ìròyìn tó lòde nìyí lórílẹ̀ èdè Korea látọdún tó kọjá. Ní June 28, 2018, Ilé Ẹjọ́ sọ pé bí kò ṣe sí iṣẹ́ àfidípò míì fún àwọn tí kò bá fẹ́ wọṣẹ́ ológun kò bófin mu. Nígbà tó fi máa tó bí oṣù mẹ́rin sígbà yẹn ìyẹn November 1, Ilé Ẹjọ́ Gíga kéde pé kò sẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀ tí ẹ̀rí ọkàn èèyàn kò bá gbà á láyè láti wọṣẹ́ ológun. Ìkéde yìí mú kí wọ́n dá àwọn arákùnrin wa tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n nítorí wọ́n kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun lórílẹ̀ èdè South Korea sílẹ̀, èyí sì tún mú kí ìjọba ṣòfin nípa iṣẹ́ míì tí àwọn tí kò bá fẹ́ wọṣẹ́ ológun máa ṣe.
Bí àwọn ará wa tí wọ́n gbé lórílẹ̀-èdè Korea ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ṣe ní ìgbàgbọ́ tó lágbára tí wọ́n sì jẹ́ onígboyà rán wa létí ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ yìí pé: “Jèhófà wà lẹ́yìn mi; mi ò ní bẹ̀rù. Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?”—Sáàmù 118:6.
^ ìpínrọ̀ 3 Kó tó di pé wọ́n sọ gbọ̀ngàn yìí di ibi tí wọ́n ń kó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí, ibẹ̀ ni ẹ̀wọ̀n tí wọ́n máa ń ju àwọn tó bá kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun sí lásìkò tí orílẹ̀-èdè Japan ń ṣàkóso Korea láwọn ọdún 1960 sí 1980. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lára àwọn tí wọ́n jù síbẹ̀
Ọgbà ẹ̀wọ̀n ayé àtijọ́ tó ń jẹ́ Seodaemun Prison History Hall tó wà nílùú Seoul, lórílẹ̀ èdè Korea. Ibi tí wọ́n ti kọ́kọ́ ṣe àfihàn yìí rèé ní September 2019
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan dúró níta gbọ̀ngàn tí wọ́n ti ń ṣe àfihàn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní Deungdaesa, èèyàn 51,175 ló wá ṣèbẹ̀wò síbẹ̀.
Nígbà tí wọ́n ń ṣe àfihàn náà, wọ́n jẹ́ káwọn èèyàn rí irú ìtẹ̀jáde ilé ìṣọ́ tí wọ́n ń kà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n yìí nígbà yẹn
Ọgbà ẹ̀wọ̀n kékeré kan tí wọ́n ṣe ohun tó jọ èèyàn márùn-ún sí káwọn èèyàn lè rí bí ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi àwọn Ẹlẹ́rìí sí nígbà yẹn ṣe há, tó sì nira tó
Ibi tí wọ́n ń kó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí nílùú Busan, ìyẹn Busan National Memorial Museum of Forced Mobilization under Japanese Occupation ló ṣagbátẹrù àfihàn yìí
Ibi yìí ni àfihàn náà parí sí. Wọ́n ṣe àfihàn àwòrán àwọn mẹ́rìndínláàádọ́rin (66) tí wọ́n ṣe inúnibíni sí nítorí wọn kò dá sí òṣèlú