MAY 26, 2020
SOUTH KOREA
Àwọn Òṣìṣẹ́ Ibi Àpéjọ Lórílẹ̀-Èdè South Korea Gbóríyìn Fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún Ìpinnu Wọn Láti Ṣe Àpéjọ Látorí Ẹ̀rọ
Àwọn òṣìṣẹ́ tó ń bójú tó àwọn ibi àpéjọ lórílẹ̀-èdè South Korea ti gbóríyìn fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún bá a ṣe ṣe àpéjọ agbègbè wa ti ọdún 2020 lórí ẹ̀rọ dípò ká kóra jọ síbì kan. Àwọn òṣìṣẹ́ náà gbóríyìn fún wa fún bá a ṣe fi ọ̀rọ̀ ìlera àwọn ará ìlú sọ́kàn bí a ṣe ń gbádùn àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a máa ń ṣe. Gbogbo owó tí a san sílẹ̀ láti lo àwọn ibi àpéjọ ni wọ́n ti dá pa dà.
Ọ̀kan nínú àwọn òṣìṣẹ́ ibi àpéjọ ní Seoul sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání, ohun tá a sì retí pé kí gbogbo èèyàn ṣe náà nìyẹn. A fẹ́ràn wọn gan-an ni. Gẹ́gẹ́ bí ará àdúgbò yìí, mi ò rò pé ẹ̀sìn míì wà tó ń kópa nínú ìdàgbàsókè àdúgbò bíi ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Ó ṣàlàyé pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi ire elòmíì ṣáájú tiwọn. Ó dùn wá pé wọn ò ní lè ṣe àpéjọ wọn ti ọdún yìí lọ́dọ̀ wa. A retí láti máa bá àjọṣe wa tó dán mọ́rán yìí lọ lọ́jọ́ iwájú.”
Ní Suwon, òṣìṣẹ́ ibi àpéjọ kan sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, torí pé láti nǹkan bí ọdún márùndínlógójì (35) sẹ́yìn, ni wọ́n ti ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ lo ibi àpéjọ yìí, bíi pé tiwọn ni. Àmọ́ ní báyìí, mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn jù bẹ́ẹ̀ lọ, fún títẹ̀lé àwọn ìpinnu ìjọba láti dènà bí àrùn Corona ṣe ń tàn kálẹ̀. Bí wọ́n ṣe jẹ́ ẹni tó ń gba tẹni rò wú mi lórí. Mò ń retí láti rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún tó ń bọ̀.”
Òṣìṣẹ́ kan ní pápákọ̀ òfurufú tó wà nítòsí ibi àpéjọ kan sọ pé: “Lọ́dún 2018 àti 2019, a rí i bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe wà létòlétò, àti bí wọ́n ṣe ń yára ṣe ohun tí a ní kí wọ́n ṣe. Mo mọ̀ pé torí wọ́n bìkítà nípa àwọn ẹlòmíì ni wọ́n ṣe pinnu láti má ṣe ṣe àpéjọ wọn níbí lọ́dún yìí, ìyẹn sì wú mi lórí gan-an.” Ó tún sọ pé: “Báwo ni kò bá ti dáa tó ká ní gbogbo èèyàn dà bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?”
Inú àwa èèyàn Jèhófà dùn pé a ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó ṣe yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn míì, ìfẹ́ yìí sì hàn gbangba lásìkò tí nǹkan le gan-an yìí.—Mátíù 22:39.