Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Arákùnrin Choi Young-won, Arákùnrin Baek Jong-hyun àti Arákùnrin Kang Ra-yoon. Wọ́n ń juwọ́ sáwọn mọ̀lẹ́bí wọn bí wọ́n ṣe ń lọ síbi tí wọ́n ti fẹ́ lọ ṣiṣẹ́ àṣesìnlú

NOVEMBER 23, 2020
SOUTH KOREA

Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì: Wọ́n Gba Àwọn Ará Wa Láyè Láti Ṣe Iṣẹ́ Àṣesìnlú Lórílẹ̀-èdè South Korea

Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì: Wọ́n Gba Àwọn Ará Wa Láyè Láti Ṣe Iṣẹ́ Àṣesìnlú Lórílẹ̀-èdè South Korea

Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí ìjọba Orílẹ̀-èdè South Korea máa ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú fáwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n wọṣẹ́ ológun. Ní October 26, 2020, àwọn arákùnrin mẹ́tàlélọ́gọ́ta (63) gbà láti ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú yìí, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọ̀kan lára àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà lórílẹ̀-èdè náà. Ọdún mẹ́ta ni wọ́n máa fi ṣe iṣẹ́ yìí. Wọ́n á máa se oúnjẹ fáwọn ẹlẹ́wọ̀n, wọ́n á máa bá wọn rajà, wọ́n á máa kọ́ wọn, wọ́n á máa bójú tó ìmọ́tótó àti ìlera wọn, wọ́n á sì máa tún ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ṣe. Ohun tí òfin sọ ni pé, àwọn arákùnrin yẹn ò ní lè kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n fún oṣù méjì àkọ́kọ́. Lẹ́yìn oṣù méjì yẹn, òfin gbà pé tí wọ́n bá ti parí iṣẹ́ wọn, ìdajì wọn lè lọ sípàdé, kí wọ́n sì lọ wàásù, táwọn yẹn bá dé, àwọn tó kù á wá lọ. Àmọ́, nígbàkigbà tí wọ́n bá lọ, wọ́n gbọ́dọ̀ pa dà sọ́gbà ẹ̀wọ̀n ṣáájú aago mẹ́sàn-án alẹ́.

Arákùnrin Kim Hyun-soo, tó wà lára àwọn mẹ́tàlélọ́gọ́ta (63) yẹn sọ pé: “Lóòótọ́, bí wọ́n ṣe ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú yìí yàtọ̀ pátápátá sí bí wọ́n ṣe ń ṣe é láwọn orílẹ̀-èdè míì, àmọ́ mo gbà láti ṣe é torí ó máa jẹ́ kí ń ran ìlú lọ́wọ́, kò sì ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ ológun.”

Ó dá wa lójú pé “iṣẹ́ rere” táwọn ọ̀dọ́kùnrin wa olóòótọ́ tó wà lórílẹ̀-èdè South Korea ń ṣe á túbọ̀ máa fìyìn àti ògo fún Jèhófà.​—Mátíù 5:16.

 

Arákùnrin Park Jae-hyuk ń kí àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ bó ṣe ń lọ síbi tó ti fẹ́ lọ ṣiṣẹ́

Arákùnrin Lee Sang-joon ń kó ẹrù ẹ̀ kúrò nínú mọ́tò (apá òsì). Àwọn òbí Arákùnrin Kim Yeong-hoon ń gbá a mọ́ra (apá ọ̀tún)

Arákùnrin Jeong Yeo-gyeom nígbà tó ń lọ síbi tó ti máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́