Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Mẹ́ta lára àwọn arákùnrin márùn-ún tí Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Jeonju dá sílẹ̀ lómìnira pé wọn ò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n.

JANUARY 23, 2019
SOUTH KOREA

“Wọn Ò Jẹ̀bi”

Ìgbà Àkọ́kọ́ Rèé Nínú Ìtàn South Korea Tí Ilé Ẹjọ́ Máa Dá Àwọn Tí Ẹ̀rí Ọkàn Wọn Ò Fàyè Gbà Láti Ṣiṣẹ́ Ológun Sílẹ̀ Lómìnira

“Wọn Ò Jẹ̀bi”

Ohun kan ṣẹlẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn orílẹ̀-èdè South Korea. Àwọn agbẹjọ́rò ìjọba pàrọwà fún ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn pé kí wọ́n wọ́gi lé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan márùn-ún lára àwọn arákùnrin wa kí wọ́n sì dá wọn sílẹ̀ lómìnira. Kí wá nilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ṣe? Wọ́n gba àrọwà àwọn agbẹjọ́rò ìjọba, wọ́n sì dá àwọn arákùnrin náà sílẹ̀ lómìnira. Ìpinnu tí ilé ẹjọ́ yìí ṣe ló wọ́gi lé ìdájọ́ àwọn ilé ẹjọ́ ti tẹ́lẹ̀, ó sì fi ìdí ẹ̀ mulẹ̀ pé àwọn arákùnrin náà kò ní ẹ̀sùn lọ́rùn mọ́.

December 14, 2018 ni ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ṣe ìpinnu tá à ń sọ yìí, ó sì ti wá di ìlànà òfin tá à ń tọ́ka sí láti fi pàrọwà fún àwọn ilé ẹjọ́ míì ní Korea pé kí wọ́n dá ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) àwọn arákùnrin wa sílẹ̀ lómìnira. Ní báyìí, àwọn arákùnrin tí wọ́n dá sílẹ̀ ń retí kí ìjọba ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú tí wọ́n lè ṣe dípò kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

Ohun tí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn wò ṣe ìpinnu wọn ni ìdájọ́ mánigbàgbé tí ilé ẹjọ́ méjì kan ṣe lọ́dún 2018, ìyẹn Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Korea àti Ilé Ẹjọ́ Tó Ń Rí Sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Nílẹ̀ Korea. Ìdájọ́ méjèèjì yẹn ló fòpin sí ohun kan tó ti dàṣà láti ọgọ́ta ọdún ó lè márùn-ún (65) sẹ́yìn. Ní gbogbo àsìkò yẹn, bí ẹnì kan bá sọ pé ẹ̀rí ọkàn òun ò lè jẹ́ kóun ṣiṣẹ́ ológun, ẹ̀wọ̀n lonítọ̀hún máa bára ẹ̀, bó ti wù kí àlàyé tó ṣe lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó.

Àwọn àjọ tó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn gbóṣùbà fún ilé ẹjọ́ méjèèjì yẹn torí ìpinnu tí wọ́n ṣe. Ìpinnu yẹn mú kó ṣe kedere pé ó bẹ́tọ̀ọ́ mu tẹ́nì kan bá kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀, ó ṣe tán gbogbo èèyàn ló lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ ohun tó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀. Àjọ Tó Ń Rí Sọ́ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lórílẹ̀-èdè Korea sọ pé: “Ìpinnu táwọn adájọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Korea pa ẹnu pọ̀ ṣe yẹn mú ire wa. Ó lé ní ọgọ́ta ọdún tí wọ́n ti ń fìyà jẹ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà láyè láti ṣiṣẹ́ ológun. Látìgbà yẹn, àwọn bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún (20,000) ni wọ́n ti fimú ẹ̀ dánrin. Àmọ́ ní báyìí, kò sohun tó jọ bẹ́ẹ̀ mọ́ . . . Àfi ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó ti fara da ìyà láti ọ̀pọ̀ ọdún yìí wá, a mọyì wọn gan-an, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ìdílé wọn.”

Ohun tí ìjọba ń ṣe báyìí ni pé kẹ́nì kan tó lè sọ pé ẹ̀rí ọkàn òun ò gba òun láyè láti ṣiṣẹ́ ológun, ó gbọ́dọ̀ fi ẹ̀rí ohun tó gbà gbọ́ múlẹ̀ dáadáa. Wọ́n ti fún àwọn adájọ́ ní ìtọ́ni pé kí wọ́n rí i dájú pé òótọ́ lọ̀rọ̀ ẹni náà, kì í ṣe pé ó kàn ń fi ẹ̀sìn bojú. Ẹ gbọ́ bí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣe sọ ọ́, ó ní: “Ó gbọ́dọ̀ hàn ní gbogbo apá ìgbésí ayé onítọ̀hún . . . pé òótọ́ ló ń fi ìlànà ẹ̀sìn rẹ̀ sílò.” Bí adájọ́ ṣe ń bi àwọn arákùnrin wa léèrè ọ̀rọ̀, ṣe nìyẹn mú kí wọ́n ṣàlàyé ohun tó mú kí wọ́n pinnu pé àwọn ò ní ṣiṣẹ́ ológun àti ìdí tí wọn ò fi ní jagun.—1 Pétérù 3:15.

Ó lé ní ọgọ́ta ọdún tí ìjọba ti ń ju àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Korea sẹ́wọ̀n torí pé wọn ò fẹ́ ṣe ohun tó ta ko ẹ̀rí ọkàn wọn. Èyí mú kó túbọ̀ ṣe kedere pé èèyàn àlàáfíà ni wọ́n, àlàáfíà ìlú ni wọ́n sì ń wá, torí ẹ̀ ni wọn kì í dá sọ́ràn ìṣèlú àti ogun. Ohun tó mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n ń pa èkejì lára òfin méjì tó ga jù lọ mọ́, èyí tó sọ́ pé: “Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”—Mátíù 22:39.