JANUARY 25, 2017
SOUTH KOREA
Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Rọ Ìjọba Pé Kí Wọ́n Má Ṣe Fi Òmìnira Ẹ̀rí Ọkàn Du Aráàlú
Ní December 9, 2016, Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lórílẹ̀-èdè South Korea kọ̀wé lórí báwọn èèyàn ṣe ń fẹjọ́ ìjọba sùn, Ilé Ẹjọ́ Ìjọba sì ti ń gbé e yẹ̀ wò báyìí. Ohun tí wọ́n kọ dá lórí ẹ̀tọ́ táwọn èèyàn ní láti kọ iṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn ò bá jẹ́ kí wọ́n ṣe é. Àjọ náà sọ pé tá a bá fi ojú ìlànà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn wò ó, àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ̀ pé àwọn ò ṣiṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn ò bá jẹ́ kí wọ́n ṣe é, kò sì sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n, ìjọba pàápàá ò gbọ́dọ̀ fi dù wọ́n.
Ohun tí Àjọ náà sọ nínú ìwé tí wọ́n kọ fi hàn pé èèyàn lómìnira, ó sì “bófin mu” láti sọ pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kóun ṣiṣẹ́ ológun. Àjọ náà rọ ìjọba pé, kí ọ̀rọ̀ òmìnira ẹ̀rí ọkàn tí òfin fọwọ́ sí má bàa ta ko ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ológun tóun náà ṣe pàtàkì, kí wọ́n ṣètò “iṣẹ́ àṣesìnlú tó mọ́yán lórí.”
Àjọ náà sọ pé kò nítumọ̀ bí ìjọba ṣe ń fi àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun sẹ́wọ̀n, ó ní: “Àwọn ọ̀daràn ló yẹ ká máa fìyà jẹ, torí kí ìwà ọ̀daràn lè dín kù tàbí ká tiẹ̀ lè dènà ẹ̀. Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn tí ìjọba ń fi sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun kì í kábàámọ̀ ìpinnu tí wọ́n ṣe, wọn kì í sì í yẹhùn bí wọ́n tiẹ̀ mọ̀ pé wọ́n máa fìyà jẹ àwọn. . . . A jẹ́ pé ìyà tí wọ́n fi ń jẹ wọ́n ò nítumọ̀ nìyẹn.”
Àjọ náà tún ìpinnu tí wọ́n ṣe ní December 26, 2005 sọ, pé kí ìjọba orílẹ̀-èdè Korea ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú tó máa jẹ́ káwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun ráyè sin ìjọba, lẹ́sẹ̀ kan náà, tí àwọn tó bá fẹ́ á máa bá iṣẹ́ ológun lọ kí ààbò lè wà nílùú. * Torí pé ó di dandan fún Àjọ yìí láti gbèjà ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àwọn aráàlú, wọ́n kọ èrò wọn ránṣẹ́ sí Ilé Ẹjọ́ Ìjọba kí Ilé Ẹjọ́ náà lè yiiri rẹ̀ wò.
“Òfin orílẹ̀-èdè yìí àtàwọn òfin tí ìjọba àpapọ̀ ṣe lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn fọwọ́ sí i pé àwọn aráàlú lómìnira ẹ̀rí ọkàn, tó fi hàn pé àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé àwọn ò ṣiṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn ò bá jẹ́ kí wọ́n ṣe é. Bí ìjọba ṣe ń fìyà jẹ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun yìí torí pé wọ́n ṣohun tó ta ko Òfin Iṣẹ́ Ológun, ṣe ni wọ́n ń fi òmìnira ẹ̀rí ọkàn dù wọ́n torí pé ọ̀nà míì wà tí àwọn ẹni yìí fi lè ṣe ojúṣe wọn fún ìjọba lórí ọ̀rọ̀ ààbò, ìyẹn tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ àṣesìnlú.”—Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, Ìpinnu ti November 28, 2016.
Ọ̀nà Àbáyọ
Jae-seung Lee, tó jẹ́ Ọ̀mọ̀wé Nípa Òfin sọ̀rọ̀ lórí ìpinnu tí Àjọ náà ṣe, ó ní: “Tí ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea bá sọ pé àwọn máa fọwọ́ sí i pé èèyàn ‘lẹ́tọ̀ọ́’ láti sọ pé òun ò ṣiṣẹ́ ológun, bí ìjọba àpapọ̀ lágbàáyé ṣe fọwọ́ sí i, wọ́n lè ṣètò láti fi iṣẹ́ àṣesìnlú lọ́lẹ̀. Tó bá jẹ́ pé wọ́n á ṣe bẹ́ẹ̀, màá dábàá pé kí wọ́n rí i pé àwọn tẹ̀ lé ìlànà tí ìjọba àpapọ̀ lágbàáyé ṣe lórí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ àṣesìnlú, kí ètò yìí lè ṣàṣeyọrí délẹ̀délẹ̀.”
Dae-il Hong, tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè náà sọ pé: “Láti August 2012, tí Ilé Ẹjọ́ Ìjọba ti tún sọ pé àwọn máa gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò, ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ìjọba ti rán lọ sẹ́wọ̀n. À ń retí pé kí Ilé Ẹjọ́ Ìjọba ṣe ìpinnu tó máa bá ìlànà tí ìjọba àpapọ̀ lágbàáyé fi lọ́lẹ̀ mu, èyí tó sọ pé ó yẹ kí ìjọba ka ẹ̀mí èèyàn sí, kí wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n wà ní àlàáfíà. À ń retí ọjọ́ tí ìjọba ò ní fi àwọn ọ̀dọ́kùnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n mọ́, tí wọ́n á sì lè máa ṣiṣẹ́ sìnlú wọn lọ́nà tí kò ní ta ko ẹ̀rí ọkàn wọn.”
^ ìpínrọ̀ 5 Ní July 11, 2008, Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn rọ Mínísítà Lórí Ọ̀rọ̀ Ààbò lẹ́ẹ̀kejì pé kí wọ́n ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú fáwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun, kí wọ́n sì fi lọ́lẹ̀. Bákan náà, Àjọ náà ti kọ̀wé ránṣẹ́ sí ìjọba ní November 26, 2007, wọ́n sọ pé kò tọ́ bí ìjọba ṣe ń fìyà jẹ àwọn tí wọ́n fàṣẹ pè kí wọ́n wá ṣèrànwọ́ lójú ogun léraléra, lórí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ ológun.