MARCH 1, 2018
SOUTH KOREA
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní South Korea Pàrọwà sí Ààrẹ Pé Kó Yanjú Ọ̀rọ̀ Àwọn Tí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun
Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí ní South Korea ń fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí ìjọba ṣèpinnu pàtàkì lórí bí wọn ò ṣe ní máa fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn du aráàlú. Ní December 7, 2017, Ààrẹ South Korea, ìyẹn Ààrẹ Jae-in Moon ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lórílẹ̀-èdè náà (ìyẹn Àjọ NHRC), ó sì ní kí wọ́n dábàá ohun tíjọba lè ṣe láti jẹ́ kí ọwọ́ tí wọ́n fi ń mú ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lórílẹ̀-èdè náà sunwọ̀n sí i, kí wọ́n lè dójú ìlà ìlànà tí ìjọba àpapọ̀ kárí ayé gbé kalẹ̀. Ààrẹ Moon dìídì bi Àjọ NHRC pé kí wọ́n dábàá ojútùú tí ìjọba lè pèsè sọ́rọ̀ náà, kí wọ́n lè fòpin sí òfin tí wọ́n ṣe pé káwọn ọkùnrin tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun máa ṣẹ̀wọ̀n .
Lẹ́yìn ìpàdé tí tolórí-tẹlẹ́mù gbọ́ nípa ẹ̀ yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò lákànṣe láti kàn sí àwọn èèyàn kí wọ́n buwọ́ lu ìwé tí wọ́n fẹ́ kọ ránṣẹ́ sí ààrẹ. Ìrandíran àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti jìyà gan-an torí òfin tí ìjọba ṣe pé káwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun máa lọ sẹ́wọ̀n. Ní báyìí tó sì jẹ́ pé Ààrẹ Moon ti sọ fáwọn aláṣẹ nínú ìjọba rẹ̀ pé kí wọ́n bójú tó àrọwà èyíkéyìí táwọn aráàlú bá pa, ṣe làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń rọ ààrẹ pé kó wá ojútùú sí ìṣòro táwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun ti ń kojú fún ohun tó tó àádọ́rin (70) ọdún.
Láàárín oṣù kan táwọn Ẹlẹ́rìí bẹ̀rẹ̀ àkànṣe ètò tí wọ́n ṣe yìí, wọ́n parí ẹ̀. Lára àwọn tó buwọ́ lu àwọn ìwé náà ni àwọn ọkùnrin tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá (14,000) tí ìjọba ti fìyà ọ̀daràn jẹ torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológún àtàwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26,000) tí wọ́n jẹ́ mọ̀lẹ́bí àwọn tí ìjọba dá lẹ́bi ìwà ọ̀daràn náà, tí wọ́n sì rán lọ sẹ́wọ̀n. Àwọn náà fara gbá nínú ìyà ọ̀hún lọ́nà kan.
Nígbà tó di January 15, 2018, àwọn mẹ́fà ṣojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó buwọ́ lùwé náà, tíye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógójì àti ọ̀ọ́dúnrún dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (41,275) láti kó o lọ sí Ọ́fíìsì Ààrẹ. Nínú ìwé tí wọ́n kọ, wọ́n mọrírì bí ọ̀rọ̀ náà ṣe ká ààrẹ lára, wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ìpalára tí ẹ̀wọ̀n tí wọ́n ń rán àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun lọ láti àádọ́rin (70) ọdún sẹ́yìn ti ṣe, wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní tó máa ṣe orílẹ̀-èdè náà tí wọ́n bá yanjú ọ̀rọ̀ náà. Ní January 16, 2018, Ọ́fíìsì Ààrẹ fi àwọn ìwé náà ṣọwọ́ sí Iléeṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ààbò Ìlú pé kí wọ́n gbé e yẹ̀ wò.
Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì ń ṣètò àwọn ìwé yẹn, wọ́n yan àwọn aṣojú lọ bá àwọn òṣìṣẹ́ àjọ NHRC. Wọ́n fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé ìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun. Tí ìjọba bá lè jẹ́ káwọn ọ̀dọ́kùnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ṣiṣẹ́ àṣesìnlú gẹ́gẹ́ bí àfidípò, wọn ò kàn ní jókòó tẹtẹrẹ sínú ẹ̀wọ̀n, wọ́n á wúlò fún ìjọba, wọ́n á sì wúlò fáwọn aráàlú. Àwọn òṣìṣẹ́ Àjọ NHRC sọ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, ohun tó ń fẹ́ àbójútó kíákíá làwọn máa fi ọ̀rọ̀ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun ṣe lọ́dún 2018.
Iye àwọn tí ìjọba fi sẹ́wọ̀n ní South Korea torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun pọ̀ fíìfíì ju àpapọ̀ iye wọn láwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Báwọn aláṣẹ ṣe ń yiiri òfin tí ìjọba ti ṣe látọjọ́ tó ti pẹ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí wò, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń retí pé ohun tó máa jẹ́ àbájáde ẹ̀ máa mú ìgbà ọ̀tun wá. Àpapọ̀ ohun tó lé ní ọdún mẹ́rìndínlógójì ó lé ọgọ́rùn-ún méje (36,700) táwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ti lò lẹ́wọ̀n báyìí torí pé wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun máa wá dópin.