Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ilé Ẹjọ́ Ìjọba South Korea rèé lọ́jọ́ tí wọ́n ṣe ìpinnu mánigbàgbé yẹn.

JULY 13, 2018
SOUTH KOREA

Ilé Ẹjọ́ Ìjọba South Korea Ṣèpinnu Tá A Ti Ń Retí Tipẹ́​—Wọ́n Gbèjà Àwọn Tí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun

Ilé Ẹjọ́ Ìjọba South Korea Ṣèpinnu Tá A Ti Ń Retí Tipẹ́​—Wọ́n Gbèjà Àwọn Tí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun

Láti nǹkan bí ọdún márùndínláàádọ́rin (65) báyìí làwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jẹ́ Kristẹni lórílẹ̀-èdè South Korea ti ń fi ẹ̀wọ̀n gbára torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Àmọ́ ní Thursday, June 28, 2018, ìpinnu mánigbàgbé tí Ilé Ẹjọ́ Tó Ń Rí Sọ́ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ṣe jẹ́ kọ́rọ̀ náà lójú, torí wọ́n kéde pé ohun tó wà nínú Àpilẹ̀kọ 5, ìpínrọ̀ 1, nínú Ìlànà Iṣẹ́ Ológun (MSA) ò bá òfin ilẹ̀ South Korea mu torí pé ìjọba ò ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú míì dípò iṣẹ́ ológun.

Àwọn oníròyìn rèé níwájú ìta Ilé Ẹjọ́ Tó Ń Rí Sọ́ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn. Kárí ayé làwọn oníròyìn ti ń tọ pinpin ibi tọ́rọ̀ náà dé.

Adájọ́ mẹ́sàn-án ló wà nínú ìgbìmọ̀ tó dá ẹjọ́ yìí, Adájọ́ Àgbà Lee Jin-sung sì ni alága ìgbìmọ̀ náà. Mẹ́fà nínú wọn ló fara mọ́ ìpinnu náà, àwọn mẹ́ta yòókù ta kò ó. Ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ṣe yìí máa jẹ́ kí ìjọba ilẹ̀ náà ṣe ohun táwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń ṣe káàkiri ayé, wọ́n á sì túbọ̀ jẹ́ káwọn èèyàn lómìnira láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn fẹ́, èrò ọkàn wọn àti ìgbàgbọ́ wọn.

Àwọn aṣojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Korea rèé nínú Ilé Ẹjọ́ Ìjọba kó tó di pé Ilé Ẹjọ́ náà ṣèpinnu.

Iye àwọn tí orílẹ̀-èdè South Korea ń fi sẹ́wọ̀n lọ́dọọdún torí pé wọn ò ṣiṣẹ́ ológun nítorí ẹ̀rí ọkàn wọn ju àpapọ̀ àwọn tó ń lọ sẹ́wọ̀n ní gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Ìgbà kan wà tó jẹ́ pé nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) sí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) àwọn arákùnrin wa ló ń ṣẹ̀wọ̀n lọ́dọọdún. Tí wọ́n bá sì dá wọn sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, gbogbo wọn ni wọ́n máa ń níṣòro láwùjọ torí ẹ̀sùn ọ̀daràn tó ti wà lọ́rùn wọn, tí kò sì lè pa rẹ́. Ara ohun tó sì máa ń yọrí sí ni pé kìí jẹ́ kí wọ́n ríṣẹ́ bọ̀rọ̀.

Àmọ́ nígbà tó di ọdún 2011, àwọn arákùnrin kan kọ̀wé sí Ilé Ẹjọ́ Tó Ń Rí Sọ́ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn láti fẹjọ́ sùn torí pé òfin ò ṣètò àfidípò fáwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun, àfi kí wọ́n ṣẹ̀wọ̀n. Àtọdún 2012 làwọn adájọ́ kan ti bẹ̀rẹ̀ sí í wò ó pé kò tọ́ láti máa fìyà jẹ àwọn tó jẹ́ pé òótọ́ ni ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà á kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ẹjọ́ wọn lọ sí Ilé Ẹjọ́ Tó Ń Rí Sọ́ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, kí ilé ẹjọ́ náà lè tún Ìlànà Iṣẹ́ Ológun gbé yẹ̀ wò.

Wọ́n ń fọ̀rọ̀ wá Hong Dae-il, tó jẹ́ agbẹnusọ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Korea lẹ́nu wò níwájú ìta ilé ẹjọ́ náà lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ ṣèpinnu

Iṣẹ́ Ilé Ẹjọ́ Tó Ń Rí Sọ́ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ni kí wọ́n máa wò ó bóyá òfin kan bá Òfin Ilẹ̀ Korea mu àbí ó ta kò ó. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀mejì (ìyẹn lọ́dún 2004 àti 2011) ni ilé ẹjọ́ yìí ti fọwọ́ sí i pé Ìlànà Iṣẹ́ Ológun bá òfin ilẹ̀ náà mu, àwọn náà ti wá gbà báyìí pé ó yẹ kí àtúnṣe bá a. Ilé Ẹjọ́ náà pàṣẹ pé kí ìjọba South Korea tún òfin náà ṣe, kó lè ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú míì tó jẹ́ àfidípò tó bá fi máa di ìparí ọdún 2019. Lára àwọn iṣẹ́ àṣesìnlú tí wọ́n lè ní káwọn èèyàn máa ṣe ni pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nílé ìwòsàn tàbí láwọn àjọ míì tó ń ṣèrànwọ́ fún aráàlú, àmọ́ tí kò sí lábẹ́ àwọn ológun.

Ká lè mọ bí ìpinnu yìí ti ṣe pàtàkì tó, Arákùnrin Hong Dae-il, tó jẹ́ agbẹnusọ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Korea sọ pé: “Ilé Ẹjọ́ Tó Ń Rí Sọ́ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, tó jẹ́ ilé ẹjọ́ tó lágbára jù lórílẹ̀-èdè yìí tó ń gbèjà ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, ti fojú ọ̀nà àbáyọ kan hàn sọ́rọ̀ yìí. Àwọn arákùnrin wa ń retí ìgbà tí wọ́n máa lè ṣiṣẹ́ sìnlú lọ́nà tí ò ní pa ẹ̀rí ọkàn wọn lára, tó sì máa bá ohun táwọn orílẹ̀-èdè yòókù kárí ayé ń ṣe mu.”

Lára àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì míì tá a ṣì ń retí kó lójú ni ọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jẹ́ igba ó dín mẹ́jọ (192) tó ń ṣẹ̀wọ̀n lọ́wọ́lọ́wọ́ torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun, àtàwọn ẹjọ́ míì tó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) tó ṣì wà láwọn ilé ẹjọ́ káàkiri orílẹ̀-èdè náà.

Ìpinnu mánigbàgbé tí Ilé Ẹjọ́ Tó Ń Rí Sọ́ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ṣe máa jẹ́ kó túbọ̀ ṣeé ṣe fún Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ láti dá àwọn tí wọ́n bá gbọ́ ẹjọ́ wọn lórí ọ̀rọ̀ yìí láre. Ibi tí gbogbo àwọn adájọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ bá fẹnu kò sí máa pinnu ohun tí ilé ẹjọ́ máa ṣe lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tọ́rọ̀ kàn.

A retí pé tó bá di August 30, 2018, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ máa ṣe àpérò kan láti jíròrò ọ̀rọ̀ náà, tó bá sì yá, wọ́n á ṣèpinnu. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn máa jẹ́ láti ọdún mẹ́rìnlá (14) sẹ́yìn tí gbogbo àwọn adájọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ máa gbé ọ̀rọ̀ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun yẹ̀ wò.

Kó tó dìgbà yẹn, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Korea ti ń báṣẹ́ lọ lórí bí wọ́n ṣe máa ṣàtúnṣe sí Ìlànà Iṣẹ́ Ológun.

Arákùnrin Mark Sanderson tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ pé: “Ara wa ti wà lọ́nà láti gbọ́ ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ máa ṣe. Tinútinú làwọn arákùnrin wa ní Korea ti ń yọ̀ǹda bí wọ́n ṣe ń fi òmìnira wọn dù wọ́n, torí wọ́n mọ̀ pé ‘bí ẹnì kan, nítorí ẹ̀rí-ọkàn sí Ọlọ́run, bá ní àmúmọ́ra lábẹ́ àwọn ohun tí ń kó ẹ̀dùn-ọkàn báni, tí ó sì jìyà lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu, èyí jẹ́ ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà.’ (1 Pétérù 2:19) A bá wọn yọ̀ torí ilé ẹjọ́ ti gbà báyìí pé ṣe ni wọ́n ń rẹ́ wọn jẹ látọdún yìí wá, àti pé wọ́n fìgboyà dúró lórí ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn fẹ́.”