FEBRUARY 9, 2016
SOUTH KOREA
Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lábẹ́ Ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Rọ Ìjọba Orílẹ̀-èdè South Korea Pé Kí Wọ́n Fọwọ́ sí Ẹ̀tọ́ Láti Kọ Ohun tí Ẹ̀rí Ọkàn Ẹni Kò Gbà Láyè
Lẹ́yìn tí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ọwọ́ tí orílẹ̀-èdè South Korea fi ń mú ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn látẹ̀yìnwá, ìgbìmọ̀ náà sọ ibi tí wọ́n parí èrò sí ní November 3, 2015. Ìgbìmọ̀ náà rí i pé ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea ti sapá láti rí i pé wọn ò fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn du àwọn aráàlú, àmọ́ wọ́n kíyè sí i pé ìjọba ò tíì ṣe ohun tí Ìgbìmọ̀ náà ní kí wọ́n ṣe nípa àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò gbà láyè láti ṣiṣẹ́ ológun.
Ẹ̀tọ́ Láti Ṣe Ohun tí Ẹ̀rí Ọkàn Ẹni Bá Fẹ́ àti Ẹ̀sìn Tó Wuni
Kárí ayé ni òfin ti fọwọ́ sí i pé kálukú ní ẹ̀tọ́ láti kọ iṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò bá fàyè gbà á. Àmọ́ ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea ṣì ń fìyà jẹ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò gbà láyè láti ṣiṣẹ́ ológun. Látọdún 1950, ilé ẹjọ́ ti rán àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) lọ sẹ́wọ̀n, tá a bá sì ṣí ọdún tí gbogbo wọn ti lò lẹ́wọ̀n pọ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì (36,000) ọdún.
Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè rọ ìjọba pé:
Kí wọ́n tú gbogbo àwọn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè láti ṣiṣẹ́ ológun sílẹ̀ ní kíákíá.
Kí wọ́n pa ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kan àwọn wọ̀nyí rẹ́, kí wọ́n sanwó gbà-máà-bínú fún wọn, kí wọ́n sì rí i pé ìsọfúnni ara ẹni tí wọ́n ti ní nípa àwọn èèyàn yìí ò di èyí tí tajá tẹran mọ̀ nípa rẹ̀.
Kí wọ́n má fìyà jẹ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò gbà láyè láti ṣiṣẹ́ ológun, kí wọ́n sì fún wọn láǹfààní láti ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú dípò iṣẹ́ ológun.
Ó Yẹ Kí Ìjọba Tẹ̀ Lé Àdéhùn Tó Fọwọ́ Sí
Láti ọdún 2006, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe Ìpinnu márùn-ún tó dá ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea lẹ́bi torí pé wọ́n ń fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè láti ṣe ohun kan dù wọ́n, wọ́n sì ń fìyà jẹ àwọn tó gùn lé ẹ̀tọ́ wọn. * Ìgbìmọ̀ náà tún rọ ìjọba lẹ́nu àìpẹ́ yìí láti “gbé ìgbésẹ̀, kí wọ́n ṣètò tó yẹ kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ lórí àwọn Ìpinnu tí Ìgbìmọ̀ náà ṣe,” kí wọ́n sì ṣe gbogbo ohun tí Ìgbìmọ̀ náà ní kí wọ́n ṣe.
Lẹ́yìn ohun tí Ìgbìmọ̀ náà sọ, Seong-ho Lee tó jẹ́ alága Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lórílẹ̀-èdè Korea, gbà pé òótọ́ lohun tí Ìgbìmọ̀ náà sọ pé àwọn fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn du àwọn aráàlú. Nígbà tí Ọ̀gbẹ́ni Lee ń rọ ìjọba pé kí wọ́n gbé ìgbésẹ̀ lórí ohun tí Ìgbìmọ̀ náà ní kí wọ́n ṣe, ó sọ pé: “Ó yẹ kí ìjọba ṣe ohun tí wọ́n fọwọ́ sí nínú àdéhùn ICCPR [International Covenant on Civil and Political Rights], láti má fi ẹ̀tọ́ àwọn aráàlú dù wọ́n.”
South Korea wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tó ti fọwọ́ sí àdéhùn ICCPR, pé àwọn ò ní fi ẹ̀tọ́ aráàlú dù wọ́n. Nígbà tó sì ti jẹ́ pé Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ló ń rí sí i pé àwọn orílẹ̀-èdè ò yẹ àdéhùn ICCPR, tí wọ́n sì gbà pé ẹnì kan lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò gbà láyé, a jẹ́ pé orílẹ̀-èdè South Korea jẹ̀bi torí wọ́n rú òfin náà, àfi tí wọ́n bá tẹ̀ lé Ìpinnu tí Ìgbìmọ̀ náà ṣe, tí wọ́n sì ṣe ohun tó sọ ni ọrùn wọn á tó mọ́.
Kárí ayé ni àwọn èèyàn ò ti fọwọ́ sí ohun tí ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea ń ṣe fún àwọn tó kọ ohun tí ẹ̀rí ọkàn ò gbà wọ́n láyè láti ṣe, ohun tí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sì sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé àwọn náà ò fara mọ́ ọn. Púpọ̀ lára àwọn tó ń gbé ní South Korea àtàwọn orílẹ̀-èdè míì ló ń fara balẹ̀ wo ohun tí ìjọba máa ṣe ní báyìí tí wọ́n ti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọn ò ṣe ojúṣe wọn.
^ ìpínrọ̀ 10 Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè máa ń ṣe àwọn Ìpinnu tí wọ́n bá rí i pé orílẹ̀-èdè kan ti yẹ àdéhùn ICCPR tó fọwọ́ sí. Ìwọ̀nyí ni àwọn Ìpinnu tó jẹ́ kí ìjọba South Korea mọ̀ pé wọ́n ti rú òfin tó wà ní Àpilẹ̀kọ 18, tó dá lórí “òmìnira láti ronú, láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn ẹni bá fẹ́ àti ẹ̀sìn tó wuni”: 1321-1322/2004, Yeo-bum Yoon and Myung-jin Choi v. Republic of Korea, November 3, 2006; No. 1593-1603/2007, Eu-min Jung et al. v. Republic of Korea, March 23, 2010; No. 1642-1741/2007, Min-kyu Jeong et al. v. Republic of Korea, March 24, 2011; No. 1786/2008, Jong-nam Kim et al. v. Republic of Korea, October 25, 2012; No. 2179/2012, Young-kwan Kim et al. v. Republic of Korea, October 15, 2014.