Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 18, 2019
SOUTH KOREA

Àwọn Ará ní South Korea Ní Ìgbàgbọ́ àti Ìgboyà​—⁠Wọ́n Kọ̀ Láti Wọṣẹ́ Ológun

Àwọn Ará ní South Korea Ní Ìgbàgbọ́ àti Ìgboyà​—⁠Wọ́n Kọ̀ Láti Wọṣẹ́ Ológun

Látọdún 1953 ni ìjọba orílẹ̀-èdè Korea ti ń fi àwọn arákùnrin tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ sẹ́wọ̀n nítorí àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Lápapọ̀, àwọn arákùnrin tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà mọ́kàndínlógún (19,000) ló ti lo àpapọ̀ iye ọdún tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́rìndínlógójì (36,000) lẹ́wọ̀n torí wọ́n ò yẹhùn lórí ìgbàgbọ́ wọn. Àmọ́, ní February 28, 2019, wọ́n dá èyí tó kẹ́yìn lára àwọn arákùnrin wa tó wà lẹ́wọ̀n sílẹ̀. Báwo nirú àyípadà ńlá yìí ṣe ṣẹlẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo ìtàn nípa bí àwọn ará wa ni Korea ṣe fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ tó lágbára àti pé àwọn jẹ́ onígboyà.