Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 1, 2018
SOUTH KOREA

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Nílẹ̀ South Korea Dá Ẹjọ́ Mánigbàgbé

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Nílẹ̀ South Korea Dá Ẹjọ́ Mánigbàgbé

Ní Thursday, November 1, 2018, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Nílẹ̀ South Korea dájọ́ pé ẹni tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò bá jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun ò hùwà ọ̀daràn kankan. Àwọn adájọ́ mẹ́rin ò fara mọ́ ìdájọ́ yìí, àmọ́ àwọn mẹ́sàn-án ló fara mọ́ ọ. Ní báyìí, wọ́n máa fàyè gba ẹni tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò bá gbà á láyè láti ṣiṣẹ́ ológun nítorí ẹ̀sìn rẹ̀. Àwọn ilé ẹjọ́ lóríṣiríṣi nílẹ̀ Korea sì lè tẹ̀ lé ìdájọ́ mánigbàgbé tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣe yìí, kí wọ́n sì dá àwọn ará wa tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn (900) láre nígbà tí wọ́n bá ń gbọ́ ẹjọ́ wọn tó wà nílẹ̀.

Ní oṣù mélòó kan sẹ́yìn, Ilé Ẹjọ́ Ìjọba Korea dájọ́ pé tó bá fi máa di oṣù December 2019, kí ìjọba ti ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú míì fún àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

Inú wa dùn, a sì yin Jèhófà nítorí ìdájọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí.