Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lee Gyo-won tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣẹ̀wọ̀n ọdún kan ààbọ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ní Daegu Detention Center torí pé ó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Òun àtàwọn míì tó lé ní ọgọ́rùn-ún tó wà lẹ́wọ̀n ń retí àpérò tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ fẹ́ ṣe ní August 30, tí wọ́n á ti bójú tó ọ̀rọ̀ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

AUGUST 24, 2018
SOUTH KOREA

Ẹnì Kan Tí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kó Ṣiṣẹ́ Ológun Ń Fayọ̀ Retí Ìgbẹ́jọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ

Ẹnì Kan Tí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kó Ṣiṣẹ́ Ológun Ń Fayọ̀ Retí Ìgbẹ́jọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ

ÌLÚ SEOUL, South Korea—Ní January 2017, Lee Gyo-won tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún (21) nígbà náà dúró níwájú adájọ́ kan nílẹ̀ South Korea. Ó ti múra ohun tó máa sọ sílẹ̀ dáadáa, ó sì retí pé ibi ire lọ̀rọ̀ náà máa já sí. Ọ̀gbẹ́ni Lee ní in lọ́kàn pé òun máa mú kí adájọ́ náà gbà pé ìwà ọ̀daràn kọ́ lòun hù bóun ṣe sọ pé òun ò wọṣẹ́ ológun, ẹ̀rí ọkàn òun ni ò jẹ́ kóun ṣe é torí òun gbà gbọ́ pé kò yẹ kéèyàn máa hùwà ipá sí ọmọnìkejì.

Kò fi bẹ́ẹ̀ sídìí tó fi yẹ kí Ọ̀gbẹ́ni Lee tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa retí pé ilé ẹjọ́ máa dá òun láre. Ìdí ni pé nígbà tí ìgbẹ́jọ́ ẹ̀ bẹ̀rẹ̀, ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó dín mẹ́jọ (392) làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lẹ́wọ̀n, àròpọ̀ iye ọdún tí wọ́n sì máa lò níbẹ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé méjìdínláàádọ́rùn-ún (588). Látọdún 1950, ó ju ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlógún ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ogójì (19,340) àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi ti Ọ̀gbẹ́ni Lee tó ti lo àpapọ̀ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (36,800) ọdún lẹ́wọ̀n torí pé òfin ilẹ̀ Korea ò fọwọ́ sí i pé èèyàn lè tìtorí ohun tó gbà gbọ́ sọ pé òun ò ṣiṣẹ́ ológun.

Àmọ́ látọdún 2004, àwọn adájọ́ tí kò fara mọ́ bí ilé ẹjọ́ ṣe ń rán irú àwọn bẹ́ẹ̀ lọ sẹ́wọ̀n ti dá àádọ́rùn-ún (90) lára wọn láre pé wọn ò jẹ̀bi. Bí àpẹẹrẹ, Adájọ́ Àgbà Choi Jong-du ti Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti ìlú Busan gbà pé téèyàn kan bá pinnu pé òun ò ní wọṣẹ́ ológun, “ohun tí ẹ̀sìn ẹ̀ gbà, tó sì ti fi kọ́ ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀.”

Ní June 2018, Ilé Ẹjọ́ Ìjọba South Korea pinnu pé ìjọba gbọ́dọ̀ tún Ìlànà Iṣẹ́ Ológun ṣe, kó lè fàyè gba àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun láti ṣiṣẹ́ àṣesìnlú míì. * Àmọ́ ìgbà tí ilé ẹjọ́ fi máa ṣèpinnu yẹn, ó ti bọ́ sórí fún Ọ̀gbẹ́ni Lee. Ó sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe kí n lè pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, ọgbà ẹ̀wọ̀n ni mo wà báyìí ní Daegu Detention Center.” Ọdún kan ààbọ̀ ló máa lò níbẹ̀.

Láti ayé ìgbà táwọn ará Japan ti ń jọba lórí Korea ni wọ́n ti ń rán àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun, Ọ̀gbẹ́ni Lee náà sì ti wà lára wọn báyìí. Nígbà tí ìjọba rán àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ sẹ́wọ̀n ní Japan lọ́dún 1939 torí pé wọn ò wọṣẹ́ ológun, ńṣe làwọn aláṣẹ mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yòókù tó wà ní Japan, Taiwan àti Korea (tí wọ́n mọ̀ sí Chosun nígbà yẹn). Àwọn Ẹlẹ́rìí méjìdínlógójì (38) tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n ní Korea nígbà yẹn ò júbà alákòóso ilẹ̀ Japan, wọn ò sì lọ́wọ́ sí ogun. Márùn-ún lára wọn ló kú sẹ́wọ̀n lọ́wọ́ ìwà ìkà tí wọ́n ń hù sí wọn níbẹ̀, ìgbà tí orílẹ̀-èdè Japan fìdí rẹmi nínú ogun lọ́dún 1945 ni ọ̀pọ̀ nínú wọn tó dòmìnira.

Díẹ̀ lára àwọn 19,340 tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n ti ṣẹ̀wọ̀n torí ẹ̀rí ọkàn.

Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún (100) ọdún táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ti ń wọṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn wọn. Ohun tí Bíbélì sọ àti ohun táwọn Kristẹni ayé àtijọ́ ṣe ló mú kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé kò yẹ káwọn Kristẹni máa lọ́wọ́ sí ogun torí pé wọn ò lẹ́tọ̀ọ́ láti gbẹ̀mí èèyàn. Ohun míì tí kì í tún jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí dá sí òṣèlú ni pé ọmọ Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n ka ara wọn sí.

Ìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà (tí wọ́n mọ̀ sí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn) kọ́kọ́ kojú ìṣòro torí pé wọn ò fẹ́ hùwà ipá. Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló kọ̀ láti jẹ́ ìpè ìjọba pé kí wọ́n wá wọṣẹ́ ológun ní dandan. Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló pọ̀ jù lára àwùjọ èèyàn tó wà lẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun, wọ́n tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti ogójì (4,440).

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbà ìjọba Násì tí wọ́n jẹ́ apàṣẹwàá ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kojú àdánwò tó le jù lórí ọ̀rọ̀ ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Àkọsílẹ̀ tó kún rẹ́rẹ́ fi hàn pé nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ìjọba Násì pa, torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun ni wọ́n ṣe pa èyí tó pọ̀ jù lára wọn. Ó ju ẹgbẹ̀rún kan (1,000) Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kú torí ìyà tí wọ́n fi jẹ wọ́n àti ìwà ìkà tí wọ́n ń hù sí wọn lọ́gbà ẹ̀wọ̀n torí pé wọn ò yẹ ìgbàgbọ́ wọn. Bí òpìtàn Robert Gerwarth ṣe sọ ọ́, àwọn “nìkan ni wọ́n ṣe inúnibíni sí láyé ìgbà ìjọba Násì torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́.”

Nínú gbogbo ilẹ̀ tí wọ́n ti ń fìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí ọkàn, ti ilẹ̀ Korea ló tíì pẹ́ jù lọ. Nígbà tí Lee Gyo-won wà lọ́mọ ọdún mẹ́jọ, bàbá ẹ̀ kú nínú jàǹbá ọkọ̀, ìyá ẹ̀ ló sì kọ́ ọ nípa Bíbélì àti ìdí tó fi ṣe pàtàkì kó má ṣe ohun tó ta ko ẹ̀rí ọkàn ẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Lee sọ pé, “Nígbà tí mo rí ìdí tí Ọlọ́run fi dá wa sáyé, ó mú kí n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, Ọlọ́run mi. Àtìgbà yẹn ni mo ti pinnu pé Jèhófà ni màá fi gbogbo ayé mi sìn, ohun tó sì gbawájú lọ́kàn mi nìyẹn.”

Torí pé Ọ̀gbẹ́ni Lee ti mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kóun ṣẹ̀wọ̀n lọ́jọ́ kan, ó ti lọ kọ́ṣẹ́ tó jẹ mọ́ ilé kíkọ́. Ó ti ní in lọ́kàn pé tóun bá ti kúrò lẹ́wọ̀n, òun á máa ṣiṣẹ́ ara òun, torí ó mọ̀ pé ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n ti fi kan òun lábẹ́ òfin máa jẹ́ kó ṣòro fóun láti ríṣẹ́.

Ọ̀gbẹ́ni Lee rántí ọjọ́ tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, ó ní, “Ó wù mí gan-an láti jẹ́ kí ilé ẹjọ́ rí i pé mi ò jẹ̀bi, ó ṣe tán, ohun tí mo gbà gbọ́ àti ẹ̀rí ọkàn mi ló jẹ́ kí n ṣe ìpinnu tí mo ṣe.” Ó rántí àwọn Kristẹni ayé àtijọ́ bíi Sítéfánù àti Pọ́ọ̀lù, tí wọ́n gbèjà ìgbàgbọ́ wọn lọ́nà tó wọni lọ́kàn nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ wọn. Ọ̀gbẹ́ni Lee sọ pé, “Ó jọ pé mo sọ̀rọ̀ dáadáa nílé ẹjọ́ ju bí mo ṣe fi dánra wò lọ.”

Tó bá di August 30, 2018, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní South Korea máa ṣe àpérò kan lórí ohun tí Ilé Ẹjọ́ Ìjọba sọ pé kí wọ́n ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú míì fún àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ bá ṣe máa nípa tó lágbára lórí ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) ẹjọ́ tó wà nílẹ̀ láwọn ilé ẹjọ́ káàkiri. Bákan náà, àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́tàdínlọ́gọ́fà (117) tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun, tí wọ́n ṣì wà lẹ́wọ̀n, títí kan Ọ̀gbẹ́ni Lee, ti kọ̀wé lọ́nà àkànṣe sí ààrẹ orílẹ̀-èdè South Korea pé kó dá àwọn sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, wọ́n sì ń retí èsì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọ̀gbẹ́ni Lee ṣì lè wà ní Daegu Detention Center ní August 30, tayọ̀tayọ̀ ni á fi máa ṣèwádìí ibi tí wọ́n bá ẹjọ́ náà dé.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹjọ́ dá Ọ̀gbẹ́ni Lee lẹ́bi, tí wọn ò sì gba ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó pè, ó ń retí pé dídùn lọsàn máa so fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi tòun. Ó ní: “Àdúrà mi ni pé kí n wà lára àwọn tó gbẹ̀yìn tó máa dèrò ẹ̀wọ̀n, kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, ìfẹ́ tí mo ní sí àwọn míì àti pàápàá jù lọ, ìfẹ́ tí mo ní sí Ọlọ́run mi àtàwọn ìlànà rẹ̀ ló sọ mi dèrò ẹ̀wọ̀n yìí.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: Paul S. Gillies, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

South Korea: Hong Dae-il, +82-31-690-0055