Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 30, 2018
SOUTH KOREA

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Nílẹ̀ South Korea Gbọ́ Tẹnu Àwọn Èèyàn Lórí Ọ̀rọ̀ Àwọn Tí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Nílẹ̀ South Korea Gbọ́ Tẹnu Àwọn Èèyàn Lórí Ọ̀rọ̀ Àwọn Tí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun

Ní Thursday, August 30, 2018, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Nílẹ̀ South Korea ṣe àpérò kan lórí ẹjọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́ta kan tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun, àwọn adájọ́ mẹ́tàlá ló sì gbọ́ ẹjọ́ náà. Wákàtí mẹ́rin ni gbogbo àwọn adájọ́ mẹ́tàlá náà fi béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn agbẹjọ́rò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn míì nípa ọ̀rọ̀ tó ti ń jà ràn-ìn nílẹ̀ tipẹ́tipẹ́ torí bí wọ́n ń ṣe ju àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun sẹ́wọ̀n ní Korea. Àwọn adájọ́ náà sọ̀rọ̀ gan-an nípa ẹjọ́ mánigbàgbé tí Ilé Ẹjọ́ Ìjọba dá ní June 28, 2018, tó fi pàṣẹ fún Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Korea pé kí wọ́n ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú míì fáwọn tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè láti ṣiṣẹ́ ológun dípò kí wọ́n máa jù wọ́n sẹ́wọ̀n bí ọ̀daràn. Àwọn agbẹjọ́rò náà ní kí Ilé Ẹjọ́ dá àwọn arákùnrin mẹ́ta yìí láre, kí ọ̀rọ̀ wọn lè jẹ́ àpẹẹrẹ tó máa ṣeé tẹ̀ lé nígbà táwọn ilé ẹjọ́ míì bá fẹ́ yanjú irú ẹjọ́ yìí tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) tó ṣì wà nílẹ̀. Ní báyìí, ó kù sọ́wọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ láti sọ ìgbà tí wọ́n máa dá ẹjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó lápẹẹrẹ tí wọ́n gbé yẹ̀ wò yìí àti ibi tí wọ́n máa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà já sí.

Àwa àti àwọn arákùnrin wa olóòótọ́ tó lé ní ọgọ́rùn-ún (100) tó ṣì wà lẹ́wọ̀n kò ní jẹ́ kó sú wa bá a ṣe ń fi sùúrù dúró dé Ọlọ́run ìgbàlà wa.—Míkà 7:7.