Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Díẹ̀ rèé lára àwọn aṣojú, àwọn agbẹjọ́rò àtàwọn míì tó kọ̀wé sí ìjọba pé kí wọ́n yé fìyà jẹ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn kò gbà láyè láti ṣe iṣẹ́ ológun

SEPTEMBER 8, 2017
SOUTH KOREA

Ọ̀pọ̀ Èèyàn Sọ Pé Ó Yẹ Kí Ìjọba South Korea Bọ̀wọ̀ fún Ẹ̀tọ́ Àwọn Tí Kò Fẹ́ Wọṣẹ́ Ológun

Ọ̀pọ̀ Èèyàn Sọ Pé Ó Yẹ Kí Ìjọba South Korea Bọ̀wọ̀ fún Ẹ̀tọ́ Àwọn Tí Kò Fẹ́ Wọṣẹ́ Ológun

Àwọn ará ìlú South Korea ti bẹ̀rẹ̀ sí í fẹnu kò lórí ọ̀rọ̀ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà láyè láti wọṣẹ́ ológun látìgbà tí wọ́n ti gbọ́ ẹjọ́ tó wáyé ní July 2015. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹjọ́ kò tíì sọ ìpinnu ìjọba South Korea lórí ọ̀rọ̀ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà láyè láti wọṣẹ́ ológun, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ló sọ èrò wọn lórí ọ̀rọ̀ yìí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ilé ẹjọ́ àdúgbò, àwọn aráàlú, àwọn agbófinró àtàwọn àjọ tó ń rí sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn nílùú àti kárí ayé ti sọ pé, ohun yòówù kí ìjọba pinnu láti ṣe sí ọ̀rọ̀ náà, wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹnikẹ́ni níyà torí pé ó ṣe ìpinnu tó bá ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mu.

Ohun Tá Ò Rò Tẹ́lẹ̀ Ṣẹlẹ̀

Ní ọ̀sẹ̀ August 7, 2017, wọ́n gbọ́ ẹjọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin méje tó sọ pé àwọn kò fẹ́ wọṣẹ́ ológun nítorí ẹ̀rí ọkàn wọn, adájọ́ sì dá wọn láre pé wọn kò jẹ̀bi rárá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí yani lẹ́nu gan-an torí ìtàn fi hàn pé ó lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógún [19,000] èèyàn tí ìjọba ilẹ̀ Korea ti ju sẹ́wọ̀n nítorí pé wọ́n kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Bẹ̀rẹ̀ láti May 2015, wọ́n dá èèyàn méjìdínlógójì [38] láre, nígbà tó máa fi di ọdún 2017, wọ́n dá èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] míì láre.

Àwọn ilé ẹjọ́ kan sún ìdájọ́ wọn síwájú kí wọ́n lè mọ ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ńlá máa ṣe, èyí ti mú kí iye ẹjọ́ tó wà nílẹ̀ pọ̀ sí i. Ọ̀gbẹ́ni Du-jin Oh tó jẹ́ agbẹjọ́rò fún ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n torí wọn ò wọṣẹ́ ológun, kíyèsí pé iye ẹjọ́ tó wà nílé ẹjọ́ ti fi ìlọ́po márùn-ún ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

Àwọn ilé ẹjọ́ kan ti ń dá àwọn tí ẹ̀rí ọkàn kò gbà láyè láti wọṣẹ́ ológun láre, (àwọn mẹ́fà ní 2015, àwọn méje ní 2016, àti àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ní 2017) àwọn tí wọn ò sì tíì dájọ́ fún túbọ̀ ń pọ̀ sí i, (nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ni wọ́n tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí wọ́n ti lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500]) èyí sì fi hàn pé àwọn agbófinró orílẹ̀-èdè South Korea ti ń tún èrò wọn pa.

Ìgbìmọ̀ aṣòfin ilẹ̀ South Korea ti tún èrò wọn pa. Ọ̀pọ̀ ilé ẹjọ́ ti rí i pé àwọn ta ko òfin tó gba aráàlú láàyè láti má ṣe ohun tí kò bá ẹ̀rí ọkàn wọn mu báwọn ṣe ń fìyà jẹ àwọn tí kò fẹ́ wọṣẹ́ ológun nítorí ẹ̀rí ọkàn wọn, àti bí ìjọba kò ṣe pèsè iṣẹ́ àṣesìnlú míì. Àwọn míì sọ pé òfin tó ń tọ́ àwọn ológun sọ́nà gan-an sọ pé tẹ́nì kan bá sọ pé ẹ̀rí ọkàn òun ò gba òun láyè láti ṣiṣẹ́ ológun, kò yẹ kí wọ́n fìyà jẹ ẹni náà.

Ohun Táwọn Aráàlú Sọ

Lóòótọ́, kì í ṣe ohun tí aráàlú bá sọ ni wọ́n fí máa ń pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, àmọ́ ẹ̀ka tó ń bójú tó ààbò ìlú, ìyẹn Ministry of Defense sọ pé ìdí táwọn ò fi ṣe nǹkan kan nípa àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà láàyè láti ṣiṣẹ́ ológun ni pé àwọn èèyàn ò sọ nǹkan kan lórí ọ̀rọ̀ náà. Ní báyìí, àwọn aráàlú tí ń sọ èrò wọn nípa ọ̀rọ̀ náà. Lọ́dún 2005, ìdá mẹ́wàá péré nínú àwọn tí wọ́n wádìí lọ́wọ́ wọn ló sọ pé kò yẹ kí wọ́n fìyà jẹ àwọn tí kò fẹ́ ṣiṣẹ́ ológun nítorí ẹ̀rí ọkàn wọn. Àmọ́, nígbà tó fi máa di May 2016, ìdá àádọ́rin [70] ló sọ pé ó yẹ kí ìjọba ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú míì tí wọ́n lè ṣe dípò tí wọ́n á fi máa fìyà jẹ wọ́n. Kódà, ní ìbámu pẹ̀lú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní July 2016, ìdá ọgọ́rin [80] nínú ọgọ́rùn-ún [100] nínú àwọn mẹ́ńbà ẹgbẹ́ Seoul Bar Association ló gbà pé kò yẹ kí wọ́n máa fìyà jẹ ẹni tí kò fẹ́ ṣiṣẹ́ ológun nítorí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀.

Ohun Táwọn Tó Ń Jà Fún Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Sọ

Àjọ kan tó ń bójú tó ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ìyẹn National Human Rights Commission of Korea (NHRC) sọ pé Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti fẹ́ ṣàtúnṣe sí òfin kí wọ́n lè ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú míì, wọ́n sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní June 2017. Ìdí ni pé ojú táwọn ará ìlú South Korea fi ń wo ọ̀rọ̀ náà ti yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀. Àjọ NHRC tún sọ pé ohun míì tó sún Ìgbìmọ̀ Aṣòfin láti fẹ́ ṣe àtúnṣe yìí ni pé àwọn orílẹ̀-èdè míì lágbàáyé rọ̀ wọ́n láti ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì tún sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú míì tó bá ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀lé lágbàáyé mu. Àjọ NHRC ti jẹ́ kí ìjọba South Korea mọ irú iṣẹ́ àṣesìnlú tí wọ́n lè ṣètò tó máa bá ìlànà táwọn orílẹ̀-èdè míì ń tẹ̀ lé mu, tí kò sì ní tako ẹ̀rí ọkàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn míì tí kò lè ṣiṣẹ́ ológún.

Wọ́n Kọ̀wẹ́ sí Ààrẹ̀ Tó Ṣèlérí

Agbẹjọ́rò tó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ni Jae-in Moon kó tó di ààrẹ ní May 10, 2017. Nígbà tó di ààrẹ, ó ṣèlérí pé: “Òfin sọ pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti yan ohun tó bá ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mu, kódà ó wà lára èyí tó gbawájú jù lọ nínú àwọn ẹ̀tọ́ tí aráàlú ní lábẹ́ òfin. Torí náà, mo ṣèlérí pé màá ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú míì tí àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà láàyè láti ṣiṣẹ́ ológun lè ṣe, kò sì sẹ́ni táa máa fi wọ́n sẹ́wọ̀n mọ́.”

Agbẹjọ́rò kan gbé ìwé tí wọ́n kọ fún òṣìṣẹ́ ìjọba kan fún àyẹ̀wò

Ní August 11, 2017, àwọn tó ń ṣojú fún ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé mẹ́rin [904] èèyàn tí kò wọṣẹ́ ológun nítorí ẹ̀rí ọkàn wọn kọ̀wé sí ààrẹ tuntun, wọ́n sọ pé kí ìjọba dá àwọn èèyàn náà sílẹ̀, torí ìyẹn ló máa fi hàn pé ìjọba bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ wọn. Wọ́n tún sọ pé kí ìjọba ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú míì tí wọ́n lè ṣe dípò iṣé ológun. Àwọn tó kọ̀wé yìí ń ṣojú fún ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ọgọ́ta [360] èèyàn tó wà lẹ́wọ̀n àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé mẹ́rìnlélógójì [544] míì tí ọ̀rọ̀ wọn ṣì wà nílé ẹjọ́ nígbà tí wọ́n kọ ìwé yìí sí ààrẹ.

Ó Jọ Pé Àyípadà Rere Máa Tó Bá Ọ̀rọ̀ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn

Hyun-soo Kim

Hyun-soo Kim tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ẹ̀rí ọkàn kò gbà láàyè láti ṣiṣẹ́ ológun sọ pé: “Mo ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí ìjọba máa gbà láti ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú míì tí kò ní sí lábẹ́ ìdarí àwọn ológun, tó sì máa bá ìlànà tí àwọn orílẹ̀-èdè míì lágbàáyé ń tẹ̀lé mu. Mo ṣe tán láti ṣiṣẹ́ míì tí wọ́n bá ní kí ń ṣe. Ó máa dáa gan-an tí mo bá ń ṣe nǹkan tó máa ṣe àwọn ará ìlú láǹfààní.”

Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn ẹlòmíì dùn bí àwọn èèyàn ṣe yí èrò wọn pa dà lórí ọ̀rọ̀ yìí, torí èyí ló máa mú kí àtúnṣe bá bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn láti ọdún yìí wá. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dúpẹ́ púpọ̀ pé Ààrẹ Moon, àwọn tó wà nílé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin àgbà, àtàwọn agbófinró ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi ojú tó tọ́ wo ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n sì ti ń bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn kò gbà láyè láti ṣe iṣẹ́ ológun.