Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MAY 9, 2016
SOUTH KOREA

Ṣé Ìjọba Ilẹ̀ South Korea Máa Fàyè Gba Òmìnira Ẹ̀rí Ọkàn?

Ṣé Ìjọba Ilẹ̀ South Korea Máa Fàyè Gba Òmìnira Ẹ̀rí Ọkàn?

Ìṣòro ńlá ni Ọ̀gbẹ́ni Seon-hyeok Kim ń dojú kọ báyìí. Ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n (28) ni ọkùnrin yìí, ó ti níyàwó, ó sì ti bímọ. Níbẹ̀rẹ̀ ọdún 2015, ọkùnrin yìí fojú ba ilé ẹjọ́ torí wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó kọ iṣẹ́ ológun torí pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò jẹ́ kó ṣe é. Torí pé ohun tó ṣe ò ta ko ìlànà tí ìjọba àpapọ̀ fi lélẹ̀ kárí ayé, Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Gwangju dá a láre. Irú ẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣẹlẹ̀ rí ní South Korea, torí àìmọye ọdún sẹ́yìn ni wọ́n ti ń dá ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun lẹ́bi, tí wọ́n sì ń tì wọ́n mọ́lé. Àmọ́, ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fagi lé ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ àkọ́kọ́ ṣe lórí ọ̀rọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Kim, wọ́n sì rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n oṣù méjìdínlógún (18). Ọ̀gbẹ́ni Kim ti wá pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Ilẹ̀ South Korea, ó ṣì ń retí ẹjọ́ tí wọ́n máa dá fún un.

Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn ilé ẹjọ́ ilẹ̀ South Korea tí ò fara mọ́ ìyà tí ìjọba ilẹ̀ náà fi ń jẹ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun ti ń pọ̀ sí i. Àwọn adájọ́ kan ti fìgboyà tẹ̀ lé ìlànà tí ìjọba àpapọ̀ fi lọ́lẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí kárí ayé, wọ́n ti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, àmọ́ ilé ẹjọ́ ti fagi lé ẹjọ́ wọn.

Ilé Ẹjọ́ Fọwọ́ sí Ẹ̀tọ́ Òmìnira Ẹ̀rí Ọkàn

May 12, 2015 ni adájọ́ Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Gwangju tó ń jẹ́ Chang-seok Choi dá Ọ̀gbẹ́ni Kim láre pé kò ṣiṣẹ́ ológun, torí èrò rẹ̀ ni pé kì í ṣe pé Ọ̀gbẹ́ni Kim ń sá fún ojúṣe rẹ̀ bí ọmọ ilẹ̀ South Korea. Àmọ́ ó gbà pé ohun tí Ọ̀gbẹ́ni Kim, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ ni ò jẹ́ kó ṣe iṣẹ́ ológun, Ọ̀gbẹ́ni Kim ò sì fẹ́ ṣe ohun tó ta ko ohun tó gbà gbọ́. Adájọ́ náà rí i pé Ọ̀gbẹ́ni Kim ṣe tán láti ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú tí ò bá ti jẹ mọ́ iṣẹ́ ológun. *

Nígbà tí Ọ̀gbẹ́ni Choi tó jẹ́ adájọ́ ń dá ẹjọ́, ó tún kíyè sí i pé òmìnira ẹ̀rí ọkàn tí Ọ̀gbẹ́ni Kim ní ló jẹ́ kó kọ iṣẹ́ ológun àti pé “kò yẹ kí wọ́n fi ẹ̀tọ́ òmìnira ẹ̀rí ọkàn táwọn èèyàn ní dù wọ́n lọ́nàkọnà.” Adájọ́ yìí ò bẹ̀rù rárá, ó gba Ọ̀gbẹ́ni Kim láyè láti má ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò fẹ́ ṣe. Ẹjọ́ tó dá ta ko ẹjọ́ tí àwọn ilé ẹjọ́ orílẹ̀-èdè náà sábà máa ń dá, àmọ́ kò ta ko ìlànà tí ìjọba àpapọ̀ fi lọ́lẹ̀ kárí ayé lórí ọ̀rọ̀ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

“Kò yẹ kí wọ́n fi ẹ̀tọ́ òmìnira ẹ̀rí ọkàn táwọn èèyàn ní dù wọ́n lọ́nàkọnà, ó sì ṣeé ṣe láti má fi ẹ̀tọ́ yìí dù wọ́n láìpa ọ̀rọ̀ ààbò orílẹ̀-èdè lára.”—Chang-seok Choi, tó jẹ́ Adájọ́ ní Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Gwangju

Àwọn tó lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ló ti kọ̀wé ránṣẹ́ sí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè, ìyẹn Ìgbìmọ̀ CCPR, wọ́n sì ti ṣe ìpinnu márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ti dẹ́bi fún ìjọba South Korea torí pé wọ́n ń fìyà jẹ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Ìgbìmọ̀ yìí ṣe ìpinnu kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí tí wọ́n ti sọ pé ṣe ni ìjọba tó bá fi àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun sẹ́wọ̀n ń tì wọ́n mọ́lé láìnídìí, èyí tó ta ko òfin bó ṣe wà nínú Àpilẹ̀kọ 9 ti àdéhùn International Covenant on Civil and Political Rights (ICCPR). * Ìgbìmọ̀ CCPR àtàwọn àjọ míì tó wà lábẹ́ ìdarí ìjọba àpapọ̀ ti rọ ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea láti ṣe òfin tó fọwọ́ sí i pé káwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun máa ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé tinútinú ni ìjọba South Korea fọwọ́ sí àdéhùn ICCPR àti Àfikún Ìlànà Àkọ́kọ́ rẹ̀ lọ́dún 1990, wọ́n kọ̀ láti tẹ̀ lé àwọn àdéhùn tí wọ́n ṣe.

Ó Jẹ̀bi àbí Kò Jẹ̀bi?

Agbẹjọ́rò kan rọ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn pé kí wọ́n fagi lé ẹjọ́ tí wọ́n dá fún Ọ̀gbẹ́ni Kim tẹ́lẹ̀, ó ní bó ṣe kọ iṣẹ́ ológun yẹn torí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò jẹ́ kó ṣe é ń fi ọ̀rọ̀ ààbò orílẹ̀-èdè náà sínú ewu. * Ní November 26, 2015, ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fagi lé ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ àkọ́kọ́ dá, wọ́n sì ní kí Ọ̀gbẹ́ni Kim lọ sí ẹ̀wọ̀n oṣù méjìdínlógún (18) torí pé ó kọ iṣẹ́ ológun.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹjọ́ náà mọ àwọn ohun tí Ìgbìmọ̀ CCPR sọ, wọ́n gbà pé ohun tí àwọn ilé ẹjọ́ ilẹ̀ South Korea bá sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí tẹ̀wọ̀n ju ohun tí òfin tí ìjọba àpapọ̀ gbé kalẹ̀ kárí ayé. Ojú ẹsẹ̀ ni Ọ̀gbẹ́ni Kim pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ, ó sì yára kọ̀wé sí Àwùjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìtinimọ́lé Láìnídìí lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè, ìyẹn UN Working Group on Arbitrary Detention. * Ó ń retí ohun tó máa ti ibi méjèèjì yìí jáde.

Léraléra ni Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ àti Ilé Ẹjọ́ Ìjọba ti ń fi ẹ̀tọ́ táwọn èèyàn ní láti kọ ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà láyè dù wọ́n. Lọ́dún 2004 àti 2011, Ilé Ẹjọ́ Ìjọba rí i pé Òfin tó de Iṣẹ́ Ológun bá òfin orílẹ̀-èdè náà mu. Ilé Ẹjọ́ Ìjọba tí wá ń tún Òfin tó de Iṣẹ́ Ológun gbé yẹ̀wò lẹ́ẹ̀kẹta kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ó bófin mu lóòótọ́, a sì ń retí kí wọ́n ṣèpinnu láìpẹ́.

Látọdún 1953, àwọn ilé ẹjọ́ ilẹ̀ South Korea ti rán àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) lọ sẹ́wọ̀n torí wọ́n kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun.

Ṣé Ìjọba Ilẹ̀ South Korea Ṣì Máa Tẹ̀ Lé Ìlànà tí Ìjọba Àpapọ̀ Fi Lélẹ̀ Kárí Ayé?

Tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ò bá gba ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Ọ̀gbẹ́ni Kim pè wọlé, ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n máa rán an lọ sẹ́wọ̀n. Ọkàn ẹ̀ ò balẹ̀ torí ó mọ̀ pé ẹ̀wọ̀n oṣù méjìdínlógún (18) tí wọ́n fẹ́ rán òun lọ yìí máa ba ìdílé òun nínú jẹ́, àtijẹ àtimu sì lè wá ṣòro fún wọn. Ìyàwó ẹ̀ nìkan láá máa gbọ́ bùkátà àwọn ọmọ wọn kéékèèké méjì, táá sì máa bójú tó wọn. Tó bá ti ẹ̀wọ̀n dé, ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn án tó sì wà lákọọ́lẹ̀ máa jẹ́ kó ṣòro fún un láti ríṣẹ́.

Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dùn pé ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè tó wà kárí ayé ń tẹ̀ lé ìlànà tí ìjọba àpapọ̀ fi lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Ọ̀gbẹ́ni Seon-hyeok Kim àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè South Korea ń retí pé káwọn ilé ẹjọ́ orílẹ̀-èdè náà yanjú ọ̀rọ̀ yìí. Ṣé Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ àti Ilé Ẹjọ́ Ìjọba máa tẹ̀ lé ìlànà tí ìjọba àpapọ̀ fi lélẹ̀ kárí ayé, èyí táwọn méjèèjì ti ṣàdéhùn pé àwọn máa tẹ̀ lé? Ṣé ìjọba ilẹ̀ South Korea máa gbà pé àwọn ọmọ ilẹ̀ náà lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò bá gbà láyè?

^ ìpínrọ̀ 5 Lọ́dún 2015, Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Gwangju dá àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́ta míì láre. Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Suwon náà dá àwọn Ẹlẹ́rìí méjì láre ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n pé wọ́n kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun.

^ ìpínrọ̀ 7 Human Rights Committee, Views, Young-kwan Kim et al. v. Republic of Korea, Communication No. 2179/2012, UN Doc. CCPR/C/112/D/2179/2012 (October 15, 2014).

^ ìpínrọ̀ 9 Agbẹjọ́rò náà sọ pé tí ẹ̀rí ọkàn ò bá jẹ́ kí ẹnì kan wọṣẹ́ ológun, ó máa wu ọ̀rọ̀ ààbò orílẹ̀-èdè náà léwu. Àmọ́ àwọn amòfin míì ò fọwọ́ sí i. Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀gbẹ́ni Gwan-gu Kim tó jẹ́ adájọ́ Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Changwon Masan sọ pé, “Kò sí ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ tó sì ṣe pàtó tàbí ìsọfúnni tó jẹ́ ká mọ̀ pé tí orílẹ̀-èdè kan bá gba àwọn èèyàn láyè láti máa ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú, ó máa wu ọ̀rọ̀ ààbò orílẹ̀-èdè náà léwu.”

^ ìpínrọ̀ 10 Tí ẹnì kan bá kọ̀wé sí àwùjọ yìí, wọ́n máa ṣèrànwọ́ kí wọ́n lè gbèjà rẹ̀ tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ mú un, tó sì jẹ́ pé lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tó ní tí òfin ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn kárí ayé fọwọ́ sí ni wọ́n ṣe fẹ́ mú un, tí wọ́n á sì tún tì í mọ́lé.