Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 30, 2018
SOUTH KOREA

Wọ́n Dá Àwọn Arákùnrin Wa Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n ní Korea

Wọ́n Dá Àwọn Arákùnrin Wa Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n ní Korea

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Korea ti fi tó wa létí pé ní November 30, 2018, mẹ́tàdínlọ́gọ́ta (57) nínú àwọn ará wa ni ìjọba dá sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, tí wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn. Gbogbo ẹgbẹ́ ará kárí ayé ló ń yọ̀ torí ohun tá a ti ń retí tipẹ́ ló ṣẹlẹ̀ yìí, a dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó ṣojúure sí wa, tó sì bù kún wa.​—Nọ́ńbà 6:​24-26.

À ń gbàdúrà fún àwọn arákùnrin mẹ́jọ tó kù lẹ́wọ̀n, a retí pé àwọn aláṣẹ máa dá wọn sílẹ̀ tí wọ́n bá ti lo oṣù mẹ́fà nínú ẹ̀wọ̀n ọdún kan ààbọ̀ tí ìjọba dá fún wọn.

Àwọn arákùnrin tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ pa dà sọ́dọ̀ àwọn òbí wọn (lọ́tùn-ún, lósì). Àwọn oníròyìn ń fọ̀rọ̀ wá arákùnrin kan lẹ́nu wò níwájú ìta ọgbà ẹ̀wọ̀n náà (àárín).