Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MAY 7, 2018
SOUTH KOREA

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Pàtẹ Ìwé Tó Dá Lórí Bíbélì Níbi Ìdíje Òlíńpíìkì àti Ìdíje Fáwọn Aláàbọ̀ Ara ti Ọdún 2018

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Pàtẹ Ìwé Tó Dá Lórí Bíbélì Níbi Ìdíje Òlíńpíìkì àti Ìdíje Fáwọn Aláàbọ̀ Ara ti Ọdún 2018

Nígbà ìdíje Pyeongchang 2018 Olympic and Paralympic Winter Games, tó wáyé ní February 9 sí 25, 2018, àti March 9 sí 18, 2018, àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin ní Korea ṣe àkànṣe ìwàásù láti jẹ́ kí àwọn àlejò lóríṣiríṣi tó wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lágbàáyé rí àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì gbà lọ́fẹ̀ẹ́.

Ó lé ní ẹgbẹ̀rún méje àti ọgọ́rùn-ún kan (7,100) àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin káàkiri orílẹ̀-èdè náà tó kópa nínú àkànṣe ìwàásù yẹn. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló wá láti ìlú Busan, Gwangju, Incheon, Seoul àti Suwon; àwọn kan tiẹ̀ wá láti Erékùṣù Jeju lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún, ibi tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) máìlì sí gúúsù Pyeongchang táwọn èèyàn ti sábà máa ń lọ gbafẹ́.

Àwọn ará wa gbé àtẹ méjìléláàádọ́jọ (152) síbi méjìdínláàádọ́ta (48) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, títí kan ibi ìgbafẹ́ Gangneung Olympic Park àti Pyeongchang Olympic Plaza. Wọ́n tún gbà wọ́n láyè kí wọ́n pàtẹ díẹ̀ lára àwọn ìwé wọn síbi àbáwọlé ọ̀kan lára àwọn ibi ìjọsìn tó wà ní Olympic Village.

Wọ́n gbé àtẹ ìwé méjì sí tòsí ẹnubodè àríwá ní Gangneung Olympic Park.

Yàtọ̀ síyẹn, àwọn aláṣẹ fún àwọn ará wa láyè láti gbé àtẹ ìwé wọn sí Gangneung Station Square tó jẹ́ ibùdókọ̀ tó gbẹ̀yìn fún ọkọ̀ ojú irin ayára-bí-àṣá tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe tán, tí wọ́n ń pè ní KTX Gyeonggang Line, èyí tó máa ń gbérò láti ìlú Incheon àti Seoul lọ sí Pyeongchang. Lọ́jọ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìdíje òlíńpíìkì, ó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà méjìdínlọ́gbọ̀n (28,000) èèyàn tó gba ibùdókọ̀ Gangneung Station kọjá.

Kí àwọn ará wa lè kàn sí àwọn àlejò tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rin (80,000) tí wọ́n ń retí pé wọ́n á wá síbi ìdíje náà, wọ́n pàtẹ ìwé ńlá, ìwé pẹlẹbẹ, ìwé ìròyìn àti àṣàrò kúkúrú lédè tó tó ogún (20), títí kan èdè Chinese, Gẹ̀ẹ́sì, Kazakh, Korean àti Russian. Bákan náà, àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin tó gbọ́ Èdè Àwọn Adití Lédè Korea dáadáa lo àwọn àtẹ tó ní móhùn-máwòrán lára láti máa fi àwọn fídíò èdè adití han ọ̀pọ̀ àwọn adití tó wá síbi Ìdíje Fáwọn Aláàbọ̀ Ara. Ìwé tí wọ́n pín lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà mọ́kànléláàádọ́rin àti igba (71,200), títí kan ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) ìwé ìkésíni wá síbi Ìrántí Ikú Kristi.

Kárí ayé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lo àtẹ ìwé tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300,000) láti pàtẹ ìwé wọn láwọn orílẹ̀-èdè tó lé ní márùndínlógójì (35). Èyí ń jẹ́ kí wọ́n lè wàásù fáwọn èèyàn níbikíbi tí wọ́n bá ti lè rí wọn, kí wọ́n sì ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ní kíkún.​—2 Tímótì 4:5.